You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde vs Oyo state teachers: Gómìnà ní àwọn Tíṣà tó fi ṣọ́ọ̀kì kọ ìdánwò sójú pátákó ní Ọ̀yọ́ fẹ́ ba òun lórúkọ jẹ́ ni
Laipẹ yii ni okiki kan pe ṣọọki lawọn olukọni kaakiri awọn ileewe alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Ọyọ fi kọ ibeere idanwo wọn soju patako nitori airi owo akoso ileewe gba lọwọ ijọba Gomina Seyi Makinde.
Ẹgbẹ awọn olukọ, NUT ni ipinlẹ naa ti lọ sori atẹgun lati pariwo sita pe oju patako lawọn olukọ kọ ibeere idanwo si fawọn akẹkọọ dipo titẹ ibeere naa sinu iwe nitori ohun ti wọn pe ni kikuna ijọba ipinlẹ naa lati san owo akoso ileewe, (school running grants) fun saa eto ẹkọ meji bayii.
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Nàìjíríà ti ní Covid-19 variant - NCDC
- Àṣírí tú! Afurasí márùn ún pa Memunat Ẹlẹ́ja àti ọlọ́kadà, wọ́n pín ẹran ara wọn sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ
- Kàyééfì rèé! Aláìsàn fìbínú lù aláìsàn ẹgbẹ́ rẹ̀ pa nítorí pé ó ń gbàdúrà lẹ́gbẹ́ rẹ̀
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
Amọṣa gomina Makinde ti ṣalaye pe, awọn ẹgbẹ olukọ naa ko fẹ tu aṣiri ara wọn sita gbangba ni ati pe o yẹ ki wọn jihin lori owo ti wọn gba ṣaaju fun akoso awọn ileewe.
Gomina Makinde ni gbogbo owo ti ijọba fun wọn ṣaaju fun akoso ileewe ni oun ni ki wọn wa ṣe iṣiro rẹ ki wọn to lee tẹwọ gba omiran.
O ni gbogbo awọn ti wọn sọ ara wọn di eku ajẹnifẹni to n jẹ owo ilu yoo foju ba ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ni ipinlẹ Ọyọ, OYACA laipẹ.