Survival fund: Èyí ni owó ìrànwọ́ #IGotSurvivalFund tí ìjọba àpapọ̀ ń fún àwọn ọmọ Nàìjíríà nítorí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19

Ijọba apapọ ṣalaye pe ni Ọjọbọ ni awọn ti bẹrẹ si ni san owo gba ma binu fun awọn eeyan ti ajakalẹ arun COVID-19 da ọrọ aje wọn ru labẹ eto owo iranwọ ti wọn pe ni MSME Survival Fund.

O dabi ẹni wi pe eyi gan lo mu ki koko ọrọ ori ayelujara, #IgotSurvivalFund o maa ja ranyinranyin loju opo ayelujara gbogbo ni Ọjọbọ.

Awọn fọto atẹjiṣẹ to n ṣafihan pe wọn ti gbowo naa lati ọdọ ijọba apapọ pẹlu itọni latọdọ ijọba apapọ pe ki wọn fi aworan rẹ han lori ayelujara pẹlu koko ọrọ ori ayelujara, #IgotSurvivalFund pe awọn ti gba owo naa.

Atẹjiṣẹ naa yoo bẹrẹ pẹlu koko ọrọ ori ayelujara naa, orukọ ẹni to janfani rẹ, orukọ ileeṣẹ rẹ, ibi ti ileeṣẹ naa wa nọmba idanimọ, ati "I am a beneficiary of Survival Fund. Thank you Federal Govt."

Owo ti wọn pin fawọn eeyan naa wa laarin ẹgbẹrun lọna ogun (N20,000) si ẹgbẹrun lọna aadọta naira, (N50,000)ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan ọdun 2020 ni iforukọsilẹ fun eto owo iranwọ naa waye gẹgẹ bi iwadii ṣe fihan, ko si di ni miliọnu kan ati ẹẹdẹgbẹrin ọmọ orilẹede Naijiria to ni okoowo to janfani owo iranwọ naa.

Nigba ti ijsba bẹrẹ eto naa ileri to ṣe ni pe idan marundinlaadọta awsn eeyan ti yoo janfani eto naa yoo jẹ obinrin, ida marun yoo jẹ awọn akanda.

Bakan naa ni wọn ṣeleri nigba naa pe awọn to wa lẹka igbokegbodo ọkọ bii awọn awakọ igbalode Bolt, atawọn oniṣẹ ọwọ bii plọmba, birikileya ati oniṣẹ ina ni yoo fẹrẹ kan julọ .