You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Deeper LifeHigh School fèsì lórí akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé wọn tí ìyá rẹ̀ ní àwọn olúkọ́ lù àti fipábálòpọ̀
Awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga Deeper Life High School ti fi sọ pe gbogbo eni ti igba iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori nitori ọrọ ọmọkunrin akẹkọọ kan ti wọn fiya jẹ lawọn yoo fimu rẹ danrin.
Ni ọsẹ to kọja ni obinrin kan figbe ta lori ayelujara pe awọn ọga ile iwe mu ọmọ oun lọ si aarin awọn akẹkọọ ti wọn si fi iya jẹ ẹ gidi.
Lara ohun to ni wọn fi ṣe ọmọ naa ni pe awọn kan n dẹyẹsi ti wọn si tun ti ika bọ nidi nitori pe o n tọọle.
Iṣẹlẹ yi waye ni ilu Akwa Ibom ti arabinrin naa si ni oun ti sọ fun awọn olukọ rẹ ṣaaju pe ọmọ naa n tọ sile ti wọn si ni o tẹ awọn lorun.
Ṣugbọn o ni ìyàlẹ́nu lo jẹ nigba ti ọga ile iwe gbe ọmọ naa kuro ni ositẹẹli rẹ lọ si aarin awọn to ju u lọ ti wọn si n ṣe iṣekuse pẹlu rẹ.
Ninu atẹjade ile iwe naa DLHS wọn salaye pe, idasile ile iwe naa ni lati fi ọrọ Ọlọ́run tọ awọn ọmọ ati lati jẹ eniyan to ni ibẹrun Ọlọrun.
Bakan naa lawọn alaṣẹ sọ pe iwadii n lọ lọwọ ati pe gbogbo eni ti igba ọrọ naa ba si mọ lori, awọn yoo fi imu rẹ danrin.
- Ẹ wo ọ̀nà àbáyọ sí ọ̀rọ̀ àgbàlagbà tò ń tọ̀ sílé
- Wo ọ̀nà to le gbà tọ́jú arúgbó rẹ lásìkò tí ọpọlọ wọn bá kù díẹ̀ lọ́jọ́ ogbó
- Àjọ ọlọ́pàá, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣàwárí òòsà tó ń mu ẹ̀jẹ̀ nílùú Ìbàdàn
- Ẹ wo ọ̀nà márùn ùn tí ọkùnrin ṣì fi ń jẹ gàba lé obìnrin lórí
- Ṣó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ tàbùkù mi torí mo ya ‘Tatoo’ sí gbogbo ara?- Olùkọ́ yarí
Wọn ni tori idi eyi, ki gbogbo ara ilu lo fi ọkan balẹ pe idajọ ododo ni awọn yoo ṣe
Ile ẹkọ Depper Life ni lọwọ lọwọ won ti ni ki ọga ile iwe naa lọ rọọkun nile nigba ti iwadii n tẹsiwaju.