Tatoo Teacher: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ń lá àlá kálàá torí àwòrán ara mi

Bi olukọ ọmọ yin ba ya 'tatoo' sara bi ti ẹni to wa ninu aworan yii, njẹ ọkan yin yoo balẹ bi?

Ọgbẹni Sylvain Helaine taa n sọrọ rẹ, jẹ olukọ ni il Faranse, oun si ni ẹni ti tatoo ara rẹ pọ julọ nilẹ naa.

Awọn akẹkọọ ileewe alakọbẹrẹ lo n kọ ni kilaasi rẹ, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹfa soke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ifọrọwanilẹnuwo, o ni obi akẹkọọ kan ti fẹjọ sun nipa bi oun ti ṣe ya tatoo sara, bo,tilẹ jẹ pe kii ṣe kilasi oun lọmọ naa wa.

''Awọn ti ko mọ mi daada ni wọn maa n foju aburu wo mi'' o sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters.

''Awọn akẹkọọ mi ko ri oun to buru ninu tatoo ti mo ya sara''

Ọgbẹni Helaine, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Freaky Hoody", sọ pe nigba ti oun kọ awọn akẹkọọ ileewe kan ni Palaiseau lẹgbẹ Paris lọdun to kọja, ni ọmọ ọdun mẹta kan sọ fawọn obi rẹ pe, n ṣe loun n la ala kala lẹyin to ri oun.

Kia lawọn obi akẹkọọ naa fẹjọ sun awọn alaṣẹ ileẹkọ.

O fẹ to oṣu meji lẹyin igba yii, ki wọn to sọ fun un pe ko ni le kọ awọn ọjẹ wẹwẹ akẹkọọ mọ.

Helaine ni ọrọ yii fọwọ kan oun lẹmi gan ni.

Helaine ko jẹ ki ọrọ yii ko irẹwẹsi ọkan ba a. O ni tatoo ti oun ya sara a maa jẹ ki oun le kọ awọn mọde ni ẹkọ nini ẹmi ifarajin sawọn eeyan miran.

O sọ fun ileeṣẹ amounmaworan BFM TV pe ''Awọn ọmọ to ba ri mi, wọn yoo kọ ẹkọ nipa ki a ma ma foju rena ẹlomiran.

Bi wọn ba dagba tan, wẹn ko ni ni ọkan idẹyẹsi, bẹẹ ni wọn ko nifoju abuku wo awọn akanda ẹda''

Ni afojuda, Helaine ni o to wakati ọtaleniirinwo ti oun fi ya awọn tatoo naa sara.

Ninu rẹ lo ni oun tun ti san owo iyebiye lati ririnajo lọ si Switzerland, lọ ya tatoo si ẹyinju oun.

O ni ofin ilẹ Faranse ko faye gba yiya iru tatoo bayi.