You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
WorldDisabilityDay: Ọdùn n dùn fáwọn àkàndá ẹ̀dá ni Akurẹ lónìí
Ajọ Differently Abled Foundation ati ajọṣepọ awọn ajọ aranilọwọ miran ti kii ṣe ti ijọba ni wọn n ṣeto sisami ayajọ ọjọ awọn akanda ẹda lagbaye tọdun 2019 ni ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo.
Papa iṣere tilu Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ni eto naa ti n lọ lọwọ ni eyi gbogbo awọn ololufẹ akanda ẹda peju pese si lati wa ṣe koriya fun wọn.
Oriṣiriṣi aworan ni akọroyin BBC, Dayọ to ba wọn peju sibẹ naa fi ranṣẹ lati fi ṣafihan ayọ awọn akanda ẹda to n sami ọdun wọn lonii.
Awọn miran ti wọn peju pesẹ si papa iṣere Akurẹ ni awọn aṣoju ijọba Ondo, awọn ẹgbẹ oniṣowo loriṣiiriṣii ti wọn ba wọn n dunnu ọjọ oni.
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ati awọn ẹgbẹ awakọ NURTW ẹka ti ipinlẹ Ondo naa ba wọn kopa ninu eto naa ni Akurẹ.
Fola ṣalye pe ko sẹni to wu lati ya akanda bẹẹni ko ẹbi ti ko le bi akanda ẹda, ṣugbọn itọju lo ṣe pataki ju.
Fọlajogun Akinlabi to jẹ adari ajọ Differently Able Foundation sọrọ kikun nipa oriṣii awọn ipenija to n koju awọn akanda ẹda bẹrẹ lati lilo ile ifowopamọsi.
Eto ti wọn ṣe ni papa isere Akurẹ naa fun awọn akanda ẹda ni anfani lati so awọn ipenija ti wọn n koju fun ijọba ati awọn ara ilu.
Arabinrin Folasade Ariṣe to jẹ aṣoju ijọba Ondo fun awọn akanda ẹda naa sọrọ lori ọna abayọ kan si iṣoro awọn akanda.
Eyi lo pe ni amuṣẹ ati ifẹsẹmulẹ ofin didẹyẹsi awọn akanda ẹda lawujọ, nibi iṣẹ, ninu ile laarin ọkunrin si obinri ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọrọ ideyẹsi awọn afin naa tun jẹyọ gẹgẹ bii akanda ẹda ti awọn eniyan mii maa n yago fun wọn bii pe wọn ni arun lara.
Alaga awọn Afin ni Ondo, ọgbẹni Ayọdele naa sọrọ lori ohun ti oju wọn n ri tọ.
Bakan naa ni wọn tun gab awọn aknada ẹda nimọran lati sa ipa lati bori ipenija wọn laiṣe ọlẹ ati pe ki ẹbi, ara, ọrẹ ẹnikẹni to jẹ akanda maa pese iranlọwọ to yẹ fun wọn loorekoore.