You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ síi nípa Oyedele Adedokun tó ya àwòràn Donald Trump tó lu ayélujára pa
Ọdọmọkunrin ayaworan ọmọ Naijiria kan, Isaac Oyedele Adedokun to ya aworan aarẹ ilẹ̀ America, Donald Trump ni iroyin nipa rẹ ti lu ayelujara pa.
Oyedele ti gbogbo eeyan mọ si doks_art lẹnu iṣẹ rẹ lo fi kalamu ya aworan aarẹ Trump to wa kede lori ayelujara pe oun fẹ ki awọn eeyan ba oun pin in titi Trump a fi rii.
Ni kete ti iroyin yii tan de ọdọ Aarẹ Trump ni oun naa ti da Oyedele lohun to gboriyin fun un pe, iṣẹ gidi lo ṣe.
Oyedele ni odiwọn aworan naa to 24 X 21 ni eyi to lo to wakati aadọrin lati fi ya.
Tani Oyedele Adedokun?
Oyedele Adedokun Isaac ni orukọ ọdọmọkunrin ayaworan yii
Oun funra rẹ lo kọ ara rẹ ni iṣẹ ayaworan, ko kọọ nibi kankan rara.
Oyedele jẹ ayaworan to n fi kalamu da ara to ba wuu ti awọn eniyan si n kọ Haa le lori nigbakigba ti o ba gbe aworan naa kalẹ bii ti Donald Trump yii.
Oyedele ni awokọṣe awujọ lo maa n jẹ iwuri lori nkan ti ohun ba fẹ ya pẹlu kalamu oun.
Ati pe ko si nkan naa to munilọkan ti oun ko le ya pẹlu kalamu oun.
Bakan naa ni Oyedele ni ipenija to n koju awọn ọdọ Naijiria maa n jẹyọ ninu iṣẹ oun loorekoore.
Oyedele ni aworan Trump to lu ayelujara pa yii ni ikeji iru rẹ ti oun maa fi ya aarẹ ilẹ̀ America.