You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Constituency office: Kí ni pàtàkì ọ́fíìsì agbègbè fún aṣòfin?
Njẹ o mọ ẹni ti o n ṣoju fun ẹkun idibo agbegbe rẹ ni ile aṣofin apapọ bi? Yala gẹgẹ bii sẹnetọ tabi aṣojuṣofin?
Lẹyin ti idibo ba ti waye tawọn oloṣelu to n du ipo gbogbo, ninu eyi ti awọn ipo ile aṣofin apapọ pẹlu wa ni wọn maa n dawati.
Opọ gba pe ti polongo ibo wọn pẹlu oniruuru agbọ-pọnula ileri fun araalu ba ti pari, ọpọ igba ni awọn oloṣelu kii boju wo ẹyin mọ titi di igba ti ọdun mẹrin miran ba ti pe ti wọn tun nilo ibo araalu.
Nitori idi eyi kii ṣe kayeefi pe lọpọ igba ati kaakiri ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria ni awọn araalu kii mọ ibi ti wọn lee wa awọn aṣoju wọn si.
- Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ẹlẹ́wọ̀n máàrún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'Eko
- Nǹkan mẹ́wàá tó yẹ ní mímọ̀ nípa fásitì ẹ̀kọ́ ìrìnà òní $50m ní Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá South Africa rí ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọdún he torí ikú ọmọ Nàìjíríà
- Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́rinlá lásìkò ìjọsìn
- Dino ní ìyàwó ni Adeyemi jẹ́ f'óun lágbo òṣèlú, Adeyemi l'ọ́mọ ọ̀dọ̀ ni Dino jẹ́
Bi o tilẹ jẹ wi pe ofin laa kalẹ pe awọn aṣofin yoo ni ileeṣẹ agbegbe lawọn ẹkun idibo wọn sibẹ ọpọ ni ko mọ ibi ti awọn ileeṣẹ wọnyii wa.
Pabanbari rẹ tilẹ ni pe ọpọ awọn aṣofin ni ko tilẹ ni awọn ileeṣẹ wọnyii.
Ki gan an ni pataki ileeṣẹ agbegbe (constituency office) fun aṣofin?
Pataki ileeṣẹ agbegbe ni lati maa gbọ aroye ati ẹdun ọkan awọn eeyan agbegbe ti irufẹ aṣofin bẹẹ n ṣoju fun.
Ọfiisi to yẹ ko ṣi silẹ gbaragada fun tẹrutọmọ ni.
Eyi tumọ si pe kii ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Sẹnetọ tabi aṣoju-ṣofin naa nikan lo lẹtọ lati maa wa sibẹ pẹlu ẹdun wọn.
Koda lati ibẹ lo yẹ ki awọn ara ilu ti maa mọ ipele to kan ninu iṣẹ akanṣe ti aṣoju wọn n gbero atiṣe fun ilu rẹ
Bakan naa lo yẹ ki wọn mọ bo ṣe n na owo ilu to n gba ni Abuja fun idagbasoke agbegbe ọhun ti wọn ba ti wọ inu ọọfiisi yii.