Crippled Folashade Adeyemo: Àwọn òbí ọ̀rẹ́ mi máa ń tilẹ̀kùn pé kí n má wọlé wọn, ká sọ̀rọ̀ wa níta

"Ojú mi gún régé nítòótọ́ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ máa ń sá fún mi ni, mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi".

Folaṣade Adeyẹmọ jẹ àkàndá ẹ̀dá ti ojú rẹ fanimọra pupọ.

Ọpọ igba lo maa n gbe aworan ara rẹ sori ayelujara ni eyi ti awọn èrò púpọ̀ máa n jẹ dòdò rẹ ṣugbọn ti wọn maa n padà wá sá fun un ni kete ti wọn ba ti ri Folaṣade ni ojukoju pe akanda ẹda ni.

Àwọn òbí rẹ̀ gbìyànjú ìtọ́tú ẹ̀sẹ̀ ọ̀hún ṣùgbọ́n ipa wọ́n pin.

O ṣalaye fun BBC Yorùbá lori idaamu ọkan rẹ lori bi awọn akẹgbẹ oun ṣe maa n yẹra fun oun nile iwe.

Folaṣade Adeyẹmọ mẹnuba oriṣi àwọn ọ̀rẹ́ lati ori ayelujara ti wọn nifẹ si oun lataari awọn fọto ti oun gbe sori erọ ayelujara ati bi wọn ṣe maa n padà sá fun oun ni kete ti awọn ba ti jọ pade lojukoju.

Ni ikẹyin, o rọ gbogbo awọn akanda ẹda lati gba kadara ki wọn mojukuro lara ihuwasi awọn eeyan kan tí òye ko yé to nipa awọn akanda ẹda lawujọ.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan ki wọn dékun ìdẹ́yẹsí àwọn akanda ẹda ati pe ki wọn fopin si titabuku wọn lawujọ nitori ko wu àwọn naa lati ri bẹẹ.