You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bola Tinubu Tattoo: Ayokunmi ní òun kọjá ààyé òun, ọkọ́ kọ̀ òun torí àwòrán bàbá ìsàlẹ̀ òun
Ọpọlọpọ eniyan lo ma n ya tatoo si ara wọn lati ṣe ara wọn loge, tabi fi ero wọn han nipa ohun ti wọn gbagbọ.
Laye atijọ, ati ọmọde ati agba ni wọn maa n kọ orukọ si ara wọn lati fi ṣe ẹsọ ara, tabi fun idanimọ ẹbi tabi ara ti eniyan ti wa.
Amọ arabinrin kan rugi oyin nigba to dapara, to tatoo baba isalẹ rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu si ara rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
Ni Oju opo ikansiraẹni Twitter, ni arabinrin AyokunmiBabato1 ti ke gbajare pe, oun ti ru igi oyin o, oun si ti kọja aye oun pẹlu aworan Tinubu ti oun ya si ẹyin oun.
O ni eebu yii ti pọju loju opo ayelujara, nitori naa ọkọ oun to si jẹ baba ọmọ oun ti le oun kuro ni ile bayii, ti oun si ti da alainilelori.
O kesi awọn eniyan loju opo Twitter ki wọn ran oun lọwọ nitori oun ṣetan lati yọ aworan ti oun ya si ara naa kuro ni kiakia.
Arabinrin naa fikun pe, inira ati eebu to tẹlẹ tatoo Tinubu ni ara oun ti pọju fun oun lati farada.
Amọ, awọn eniyan to fesi si tatoo naa ni arabinrin naa n wa ki Tinubu se akiyesi oun ni, amọ o ti wa doju rẹ bayii.
Ọkan tilẹ sọ wi pe tatoo naa dara, amọ ko yẹ ko ya a si ẹyin ara rẹ gẹgẹ bi abileko.
Igba akọkọ kọ ni yii ti awọn eniyan ti ma n ya aworan gbajugbaja eniyan si ara wọn.
Laipẹ yii ni ọmọ Naijiria ọkunrin ti o ma n mura bi obinrin, Bobrisky fun awọn ololufẹ rẹ ni ẹbun nitori wọn ya tatoo rẹ si ara wọn.