Yollywood: Mo Adebimpe gba omijé lójú Lateef Adedimeji, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí da Saheed Balogun àti Fathia Wiliams pọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọrọ ifẹ, bi adanwo ni. Eyi lo difa fun oṣere tiata Yoruba to bu sẹkun ayo. Kinni idi abajọ?

Gbogbo rẹ la o ṣalaye fun yin ni ẹkunrẹrẹ lai ṣẹ ọkan kan ku.

Saheed Balogun ati aya rẹ tẹlẹ, Fathia Willaims ṣe ọjọ ibi ni ọjọ kan naa laarin ọsẹ yii.

Wọnyii ni awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lagbo osẹre Yoruba lọsẹ yii.

Mo'bimpe gba omijé lójú Adedimeji

Gbajugbaja oṣere taita, Lateef Adedimeji ya agbado ha sawọn ololufẹ ere Yoruba lẹnu lẹyin to da omi loju poro poro.

Ki lo le mu Adedimeji bu omi loju gan an?

Ọrẹbinrin rẹ, Mo'bimpe Oyebade lo ya a lẹnu pẹlu ẹbun iyebiye ṣaaju ọjọ ibi rẹ.

Eyi lo mu ki lateef bu sẹkun ayọ

Fathia ati Saheed Balogun

Yoruba maa n sọ pe owo ti ọmọ ba ti wọ, okuta ti wọọ.

Otitọ ni pe Fathia ati Saheed Balogun ti kọ ara wọn silẹ gẹgẹ lọkọ laya bo tilẹ jẹ pe wọn bimọ fun ara wọn.

Amọ, ohun kan to maa n pa awọn mejeeji pọ lọdọọdun ni ayẹyẹ ọjọ ibi wọn.

Ọjọ karun un, oṣu keji, ọdun 2021 yii lawọn mejeeji tun ṣe ọjọ ibi wọn.

Toyin Abraham

Ilumọọka oṣere tiata, Toyin Abraham ti di wolii obinrin.

Ninu fidio kan ti Toyin fi si oju opo Instagram rẹ lo ti ṣiwaju adura fawọn obinrin ti ko ti si nile ọkọ.

Toyin sọ ninu adura naa pe ibi kibi ti wọn ko ba ni pade ọkọ wọn, ki awọn ma lọ sibẹ.

Toyin ni ki awọn obinrin ti ko ba ti lọ sile ọkọ ye ṣakọ si awọn ọkunrimọ.

Dele Odule

Agbaọjẹ oṣere Dele Odule ṣe ilanilọyẹ lori rọba idabobo fun ibalopọ ni tirẹ tori arun.

Ọgbẹni Odule sọ pe o maa n ti ọpọ eeyan loju lati beere fun rọba idaabobo nile itaja tabi ile ita oogun.

O fi ara rẹ ṣe apejuwe ẹni ti o fẹ ra rọba idaabo bo ṣugbọn ti ko le darukọ ohun to fẹ ra gan an.

Lowe lowe lo Odule fi n beere fun rọba idaabo bo lọwọ ọmọ to n taja.

Ṣugbọn ọrọ Odule ko gba ibi kan ye ọmọbinrin olutaja ọhun nitori ko sọ oju abẹ nikoo.