You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adeboye's 40th Anniversary: Ohun kan tó ń mú wa tẹ́síwájú ni pé à ń gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
"Ìyàwó mi ló n bọ́ mi nígbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀".
Lasiko ti o n sọrọ ninu iwaasu rẹ lọjọ idupẹ pe o pe ogoji ọdun lori aga gẹgẹ bi adari ijọ RCCG, Pasitọ Adeboye ni oun ko le de ibi ti oun de rara bo ba ṣe pe obinrin mii lo jẹ iyawo oun.
"Iwọ too ba ni iyawo to dara ju temi lọ, iyawo rẹ kii ṣe èèyàn ẹlẹ́ran ara".
O ni oun dupẹ fun awọn ọmọ ijọ oun pe Ọlọrun fun un wọn ni iya daadaa tii ṣe iyawor rẹ.
"Tí kìí bá ṣe pé Pa Josiah Akindayomi gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mi ò lè dé ipò tí mo wà yii torí Johnny Just Come ni mí".
Pasitọ Adeboye ni kii ṣe pe gbogbo irinajo ogoji ọdun ti o lo lori oye gẹgẹ bii adari ijọ irapada naa lo danmọran.
"Emi ati iyawo mi gba awẹ ọjọ mẹrinla pe ki n ma di Pásítọ̀ lórí ìjọ Redeem kí n tó di G.O..."
O ni ṣugbọn Ọlọrun ko gbọ, "mo dupẹ pe ko gbọ́".
Ajiṣẹ jiya ni Adeboye to jẹ pe ọdun mejidinlogun akọkọ aye rẹ ni ko fi ni bata.
Nigba to wa bẹrẹ si ni jẹ igbadun diẹdiẹ gẹgẹ bi olukọ fasiti nilu Ilorin lo ni oun yari mọ Ọlọrun lọwọ pe o pe oun lati di Pasitọ amọ Ọlọrun ko gba ti oun.
"Ile oni yara mẹrin to tun ni ile oniyara meji fun alejo ni mo ni ni ilu Ilorin, torinaa ni mo ṣe yari pe mi o fẹ gba iṣẹ iranṣẹ, mo si kọ iwe si baba mi ninu Oluwa, Pa Josiah.
Mo kọ lẹ́tà padà sí Pa Josiah pé mi ò fẹ́ jẹ G.O".
Ṣugbọn baba ni oun mọ nkan ti Ọlọrun sọ fun oun.
Adeboye ṣapejuwe iranṣẹ Ọlọrun to gbe iṣẹ le e lọ́wọ́, Pa Josiah Akindayomi gẹgẹ bii Elijah miran tori o ni ina ninu, ati pe adari ati Aposteli nla to n gbọ kedekede latọdọ Ọlọrun ni.
"Bi ori rẹ́ ba dara, gbogbo ara rẹ to ku yoo suwọn amọ, bi nkan ba n ṣe orii rẹ...".
Baba Adeboye ninu ọrọ to fi n gba awọn olujọsin niyanju gẹgẹ bi wọn ṣe n ba a dupẹ fun ogoji ọdun gẹgẹ bi oludari ijọ pe oun ko dede bẹ silẹ kija de ipo ti oun wa.
Tẹlẹ, oṣooṣu ni Adeboye ni awọn maa n gbadura gba awẹ ki wọn to lee ri owo awọn oṣiṣẹ san to si jẹ pe iyawo oun to si n ṣiṣẹ nigba naa lọhun lo n bọ idile awọn niwọn igba ti ipe si iṣẹ iranṣẹ ti ni ko fi gbogbo ile nla rẹ niluu Ilorin silẹ lati lọ tẹdo sinu igbo ọgba Redemption Camp to ti wa di ilu nla lonii.
"Asiko inira, irora, ibanujẹ, ijanikulẹ wa daadaa ṣugbọn ohun kan lo mu mi duro lati igba taa bẹrẹ irinajo naa... gbigbọ lati ọdọ Ọlọrun".
Pasitọ Adeboye ni awọn to n jowu oun lonii ko mọ ibi ti oun ti bẹrẹ bẹẹ si ni wọn o mọ orisun oun.
"Mo yọ gbogbo akọ́le Revd. Dr, BSC, MSC, PhD kúrò pẹ̀lú gbogbo ipo ti mo gba láti gbọ ipe Ọlọrun".
Ọ̀rọ̀ ìgbésúnmọ̀mí kò ni pẹ́ dópin ní Nàìjíríà- Pasítọ Adeboye
Alákoso ìjọ RCCG, Pásítọ̀ Enoch Adeboye tí fi ìdánilójú han pé, ọ̀rọ̀ ìgbésùnmọ̀mí yóò di ohún ìgbàgbé ni Nàìjíríà.
Pásítọ̀ Adeboye sọ̀rọ̀ yii ni ásìkò ìpàdé isọ́ òru olóṣooṣu.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, gbogbo ǹkan tí o bá ni ìbẹ̀rẹ̀ ni ó di dandan kí ó lópin.
Nítorí náà gbogbo àwọn tó n gbogun ti Naijiria yoo pòórá lójijì.
- Olorì Luwoo, Gbàgìdí jẹ́ obìnrin tó ṣáájú àsìkò rẹ̀ jẹ Ooni Ife tó sì tún jẹ́ alágbára gidi nílẹ̀ Yorùbá
- Dúkìá mi tó tó N500m ni mo pàdánú, àmọ́ ó wù mí láti padà sí Igangan- Seriki Fulani
- Ẹ rọra ṣe pẹ̀lú àwọn ará ìlú lásìkò yìí nítorí Covid 19- IGP Adamu Mohammed
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
Pásítọ̀ Adeboye sàlàye bí wàhálà ṣe dide si Joobu nínú bíbélì lórí gbogbo ìṣoro tó kojú, débi ti ìyàwó rẹ̀ ṣe sọ fún pé, ki o bú Ọlọ́run kí ó kú.
Bàbá Adeboye sàlàyé pé ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà loni ẹ̀sẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tí Nàìjírà ń tí Ọlọrun si n fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ olúkúlùkù, sùgbọ́n láìpẹ́ yìí yóò di oun ìgbàgbé.
Adeboye ni: "Nítorí náà mo ni ìdánilójú pé, láìpẹ́ láì jìnà, ọ̀rọ̀ ìgbésùnmọ̀mí, yóò di ohun ìgbàgbé ni Naijiria.
Koda, yoo dopin ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé míràn, nítori kìí ṣe ìgbésùnmọ̀mí ni Naìjíríà fi bẹ̀rẹ̀, nítolri náà yóò parí."
Bí Goliath ṣe dúnkooko mọ́ àwọn ọmọ israeli tó fún odidi ogójì ọjọ́, sùgbọ́n lọ́jọ́ kan ọdọ́mọkùnrin kan koju rẹ̀, tí Goliath si pàdánu ẹ,mi rẹ̀.