Kano Hisbah Police: Hisbah Kano mú ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó n ṣe káràkátà ọtí

Àwọn ọlọ́pàá Hisbah ìpinlẹ̀ Kano àti àwọn ọlọ́pàá ojú pópó (KAROTA) tí mú ọlọ́pàá kan nítorí ó ra otí fún títa àti mímu.

Ìròyìn sọ pé ọlọ́pàá kan tí wọ́n ń pè ni OC Gulder, tó tún jẹ́ Kristẹ́ní tó sì n sàkóso ilé igbáfẹ́ ọlọ́pàá Panshekara, Mopol 52 ni Sharada ìpińlẹ̀ Kano.

Wọ́n ni OC Gulder lọ si ìlú Sabon Gari láti ra otí àti àwọn ǹkan míràn láti ta ni ilé ìgbáfẹ́ ọlọ́pàá náà.

Ó ní KAROTA tí ṣọ́ ọlọ́pàá náà lọ sí ìlú náà ti wọ́n sì mú láti fàá lé Hisbah lọ́wọ́ fún ẹ̀sun pé ó ta kátọ́ọ̀nù ẹgbẹ̀rún kan ní ìpińlẹ̀ Kano.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ sọ pé, "Kìí se ọtí ló lọ pín: ó kan máa ń wá tà túnrà ni.

Onígbàgbọ́ ni ó sì ní ore-ọ̀fẹ́ láti rà tàbí ta ọtí, mó mọ̀ pé àwọn kan tí kò fẹ́ràn rẹ̀ nítórí pé òun ló n mójútó ilé ìgbáfẹ́ ọlọ́pàá ló wà lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

O salaye pe: "Ọ̀gá Ọlọ́pàá ní, A máa n pè é ni OC Gulder.

Ó sì wá sínú ibí ní sátidé tókọ́ja,

KAROTA ni Gwangwashu àti Hisbah lábẹ́ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, mótò ọlọ́pàá ni ọkùnrin náà gbé ti àwọn KAROTA fi pàdé rẹ̀ ti wọ́n sì dáa dúró, tí kò dúró fún wọ́n nítorí ọlọ́pàá ní.

O ni: "Lẹ́yìn náà ni wọ́n tẹ̀lé e tí wọ́n wá fẹ̀sùn kàn pé ó n fi mótò ọlọ́pàá pín ọtí,

Wọ́n mú u, wọ́n sì gbé e lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kan ní Sabon Gari, Ọkọ̀ Hilux mẹrin ni àwọn KAROTA gbé tí wọ́n fi lọ fẹjọ́ sun àwọn Hisbah pé ó n gbé ọtí wá si ìlú Kano.

"Leyin náà ni Hisbah pàsẹ ki wọ́n lọ kó ọtí ní sọ́ọ̀bù Emeka ni Sabo Gari ki wọ́n le fi dáran sí lọ́run, wọ́n kó ẹgbẹ̀rún kan kátọ́nù ọtí ní sọ́ọ̀bù Emeka láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọlọ́pàá náà ló ni."

"Wọ́n ti ti OC Gulder mọ́lé, kò sì sí ẹni tó mọ ìgbà ti wọ́n yóò dáa sílẹ̀.

Sáájú ni ìròyìn kàn pé, ọlọ́pàá Hisbah nípìnlẹ̀ Kano mú ọkùnrin gẹrígẹ́ri kan tó pé o gẹrun ti kò bá ìlànà Islamu mu.