Sunday Igboho vs Fulani: Mí ò nílò ìrànlọ́wọ́ owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti ilẹ̀ òkèrè

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajìjàgbara ilẹ̀ Yorùbá, Sunday Adeyemo, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ si Sunday Igboho ni ọkan oun ko mi rara ninu ijagbara lati gba iran Yoruba silẹ lọwọ awọn to pe ni apaayan Fulani darandaran bo tilẹ jẹ pe o ni ẹru n ba awọn mọlẹbi oun.

Esi yii jade lẹyin ti ti awọn kan ti ẹnikẹni ko mọ ṣi bo ọkan lara ile Sunday Igboho ni Ibadan ti wọn si jo o nina, Sunday ni ẹda alaye kankan ko lee pa oun afi Ọlọrun Ọba.

Lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Punch ló ti ṣíṣọ lójú eegún ọ̀rọ̀ pé, òun kò bèrè fún ìrànwọ́ owó láti ọwa ẹnikẹ́ni.

"Emi o bẹru ohunkohun tabi ẹnikẹni o, afi Ọlọrun. Ọlọrun lo ni ilẹ oun si ni adari gbogbo ọkan. Ko si ẹda alaye kankan to lee pami torinaa mi o le bẹru eeyan ẹlẹ́ran ara".

Ninu iroyin naa, Igboho ni awọn ọmọ oun ti n pe oun ti wọn si n rọ ọ pe ko jawọ. "Gbogbo igba ni wọn n ki mi nilọ".

"Iyawo mi naa wa ninu idamu ọkan nitori ijijagbara mi ṣugbn mo ni lati ṣe eyi fun itusilẹ awọn eeyan mi. Amọ emi naa ni ibanujẹ tori ihuwasi ti wn n ṣe si awọn eeyan mi".

Amọ Sunday ni ija yii wa fun didara gbogbo eeyan ni torii pe bi oun ba lọ tan ki wọn ma baa ṣe ẹru.

Igboho tún ṣíṣọ lójú eegún lórí ìròyìn tó n jà ràìràìn nígboro pé, Sunday Igboho ń pe fún ẹ̀bùn owó láti túbọ̀ ran ìràn Yorùbá lọ́wọ́.

Ṣáájú ni àwọn míràn tilẹ̀ sọ pé, ọ̀rọ̀ Sunday Igboho wà lára ìdí tí wọ́n fi fòfinde ètò káràkátà "Cryptocurrency" láti dènà mọ́ àwọn tó fẹ́ fi owó rànṣẹ́ sí i láti òkè òkun.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, "mí kò nílò irú owó yẹ̀n àti pé kò sí ǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀"

Ó ní owó àti ọlà tí òun ni kò ṣèyìn ìdókoowò nínú epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì, "bákan náà ni mò ń ta mọ́tò".

"Mí ò pínu láti lọ́ sínú òṣèlú gẹ́gẹ́ bi àwọn kan ṣe n sọ pẹ̀lú, bákan náà ni mí ò ṣe ǹkan ti mò ń ṣe nítori kí n le di ìlúmọ̀ọ̀ká".

Asìkò wo ni ìpàdé Sunday Igboho àti Pásítọ̀ Tunde Bakare?

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Sunday Igoho ni lóòtọ́ ni pásítọ̀ Tunde Bakare ránṣẹ́ pe òun sùgbọ́n, òun yóò jẹ́ ìpè rẹ̀ ní àsìkò tó bá ti rsrun

Kókó ọ̀rọ̀ ti a ó maa sọ náà ni bi aláfíà àti ìrọ̀rùn yóò sẹ de bá ẹ̀yà Yorùbá

Bótill jẹ́ pé , ojójúnmọ̀ ni àwọn ọmọ mi àti ìyàwó mi ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí mi lójoojúmọ́ láti má ja ìjà yiìí mọ́, sùgbọ́n ó pọndandan kí n ṣe láti le tú ìrà Yoruba sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aninilára.

Níwọ̀n ìgbà tí àwọn tó yẹ kí wọ́n mójútó ọ̀rọ̀ náà bá ti n káwọ́ gbera, mó ni ojúṣe láti ṣe fún àǹfàní ará ìlú.

Sé lọ́ọ̀tọ́ ni Sunday Igboho jó ilé Seriki fulani ní Igangan?

Ẹ jẹ́ kí n sàlàyé kí ọ̀rọ̀ le tán nílẹ̀. "Nígbà tí mo dé Eruwa, mó lọ fi ara mi hàn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá, mò sì sọ ǹkan ti mo bá wá si àdúgbò náà, adáriu ẹka ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà sì gbà láti tẹ̀lẹ́ wá lọ.

Nígbà tí a de Igangan, à tún bá àwọn 'ọlọ́pàá operation Burst' a lọ sínú ]ilú náà rán pẹ́ asì pada lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn ọlọ́pà''a.

Ìbéérè mi ni pé, ṣe ọ̀gá ọlọ́pàá yóà máa wò wá kí a lọ má dáná sun ilé Seriki? Sé ọlọ́pàá Operation Burst yóò jk kí a lọ tí a bá dáná sun ilé Seriki?

Kò sí nkan tó jọ bẹ́ẹ̀ nígbà tí a wà níbẹ̀ nítorí náà àwa kọ́ ni a dáná sun ilé Seriki Fulani.

Sunday Igboho wa gba gbogbo ọmọ Kárọ̀-oojíre nímọ̀ràn pé kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kàn kí wọ́n sìmì ọ̀rọ̀ òṣèlú ṣíṣe lórí ǹkan tó niṣe pẹlú igbésí ayé àwọn ènìyàn.

Ó rọ àwọn oríadé gbogbo, awọn ọdọ́ àti adarí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ ki wọ́n sì máa fi ohùn kan sọ̀rọ̀.

Sunday Igboho vs Fulani: Seriki ní dúkìá tó tó N500m lòun pàdánú. àmọ́ òun fẹ́ láti padà sí Igangan

Seriki Fulani ìlú Igangan, lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, Abdulkadri Saliu ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ nigba ti ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho atawọn ero lẹyin rẹ ṣe ni Igangan lẹyin to sọ fun wọn pe ki wọn fi ilẹ ipinlẹ Oyo silẹ.

Seriki ṣalaye pe owo maalu to le ni miliọnu kan naira jona mọle labẹ bẹẹdi oun.

''Dukia mi to wa nilu ile jona, ile fulati mẹrin lo jona ati kọju simi ki n kọju siọ ti mo kọkọ kọ jona,'' Seriki ṣalaye.

O ni ''maalu igba maalu le meje ni mi o ri bayii, ṣugbọn n ko le lọ wa wọn lọwọ yii, koda mo gbọ pe awọn kan ti wa n ji maalu mi lọ.

Lọrọ kan, dukia mi to bajẹ to ẹẹdẹgbẹta miliọnu ti ko ba ju bayẹn lọ,'' Seriki Saliu lo sọ bẹẹ.

Seriki Saliu ni Fulani ti wọn n jigbe ju Yoruba ti wọn jigbe ni Ibarapa lọ.

O tun ṣalaye pe ''emi gan an ni mo maa mu ẹjọ awọn Fulani lọ si agọ awọn ọlọpaa.

Nitori naa, ko si bi mo ti le jẹ baba isalẹ fawọn Fulani,'' Seriki Saliu lo sọ bẹẹ.

''Mo fẹ pada si ilu Igangan ti wọn ba gba mi laaye, bo tilẹ jẹ pe aburo mi tawọn mẹrin mii lo ba ba iṣẹlẹ ọhun lọ,'' Seriki ṣalaye.