Mohammed Adamu: Ẹ wo ìgbà mẹ́rin tí Ààrẹ Buhari ti tàpá sí ìlànà òfin orílẹ̀-èdè Nàíjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọlọpọ igba ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti rekọja ofin orilẹede Naijiria nipa titẹ oju ofin mọle.

Eleyii to ṣẹlẹ laipẹ yii ti awọn agba agbẹjọrọ lorilẹede Naijiria,SAN ti bu ẹnu atẹ lu bi aarẹ Buhari ṣe fi oṣu mẹta kun iye ọjọ ti Ọga Agba ọlọpaa, Muhammed Adamu yoo lo nipo ki o to fẹyinti lẹnu iṣẹ.

Ọjọ Ajẹ, Ọjọ Kini, Oṣu Keji lo yẹ ki Ọga Adamu fẹyinti lẹyin to wọ iṣẹ ni ọdun 1986, to si ṣiṣẹ ọba fun ọdun marundinlọgbọn.

Eyi ni akojọpọ igba mẹrin ti aarẹ Buhari ti tẹ oju ofin Naijiria mọlẹ;

1) Yiyọ olootu idajọ lorile-ede Naijiria, Adajọ Walter Onoghen kuro ni ipo

Ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Ọdun 2019 ni aarẹ Buhari paṣẹ ki Olootu idajọ lorile-ede Naijiria, Adajọ Walter Onoghen lọ rọkun nilẹ lori ẹsun magomago ti wọn fi kan an.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ aarẹ Buhari yii nitori ko ba ofin orilẹ-ede Naijiria mu.

Labẹ ofin, ẹka iṣejọba aarẹ ko lagbara lori ẹka idajọ nitori wọn da duro ni ọtọọtọ ni abẹ ofin Naijiria.

Amọ, awọn miran tilẹ ri igbesẹ aarẹ naa ni i ṣe pẹlu idibo gbogboogbo ti o waye ni ọdun 2019, ti wọn ri Onnoghen gẹgẹ bi ẹni ti yoo dena ẹto idajọ, amọ ako le e fi idi ọrọ naa mulẹ.

2) Rira ọkọ ofurufu Tucano lai gba aṣẹ lọwọ Ile Igbimọ Asofin

Ni Osu kẹrin, ọdun 2018 ni aarẹ Buhari ra ọkọ ofurufu Tucano fun ikọ ọmọogun Naijiria ni iye owo to le ni irinwo miliọnu dọla owo ilẹ okeere ($496 million).

Eleyii ni aarẹ ṣe lai gba aṣẹ ile Igbimọ Aṣofin Naijiria to si tako ofin ọdun 1999 ni orilẹ-ede Naijiria.

Ofin naa sọ wi pe aarẹ Buhari ko gbọdọ na owo ninu apo ijọba lai gba aṣẹ lọwọ Ile Igbimọ Asofin lorilẹ-ede Naijiria.

Ofin naa tun fi idi ẹ mulẹ wi pe o ni iru nkan ti ijọba le e lo owo lati apo isuna le lori to tọna labẹ ofin.

Amọ, aarẹ Buhari ko tẹlẹ ofin yii, to si ra ọkọ Tucano laigba aṣẹ ọun.

3) Atimọle Colonel Sambo Dasuki lẹyin ti ileẹjọ ti gba beeli rẹ

Ọpọlọpọ igba ni aarẹ Buhari ti kọ eti ikun si aṣẹ ileẹjọ lori ipejọ ti ijọba ba pe mọ ọmọ Naijiria.

Ileẹjọ giga ni ilu Abuja lo paṣẹ ni ọdun 2015 pe ki wọn fun Dasuki ni aṣẹ lati lọ si oke okun fun ọṣẹ mẹta lati gba eto iwosan to peye ni oke okun.

Ijọba aarẹ Buhari kọ lati bọw fun ofin ti wọn ko si gba beeli rẹ.

Ni ọdun 2016 naa ni ileẹjọ ilẹ Afrika, Ecowas paṣẹ ki wọn gba beeli rẹ, ki ijọba apapọ si san owo itanran miliọnu marundinlogun naira fun dasuki.

Bakan naa ni ọdun 2018 ni ileẹjọ tun paṣẹ bẹẹ, ti ijọba si kọ lati tẹle aṣẹ naa ti ileẹjọ pa.

4) Atimolẹ El-Zakzaky lẹyin ti ileẹjọ ti gba beeli rẹ

Adari ẹgbẹ Shite lorilẹ-ede Naijiria, El-Zakzaky ti wa ni atimọle ijọba lati ọdun mẹta lẹyin ti ikọ ọmọogun Naijiria pa awọn eniyan ni ojude.

Iyawo rẹ ati awọn ẹbi rẹ wa ni ara awọn ti wọn pa, to fi mọ ile rẹ ti wọn jo.

Lẹyin gbogbo itu ti awọn ikọ ọmọogun ṣe fun El-Zakzaky yii ni ijọba tun tii mọlẹ.

Ni ọdun 2016 ni ileẹjọ giga ni ilu Abuja paṣẹ ki wọn fi silẹ nitori ijọba lo tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.

Amọ, titi di asiko yii ni El-Zakzaky ṣi wa ni atimọle awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ti oun ati iyawo rẹ si ti lugbadi arun Coronavirus ni atimọle.

Tuntun ti Buhari ṣe ni yii:

Buhari ní kí ọ̀gá ọlọ́pàá Adamu tó yẹ kó fẹ̀yìntì máa báṣẹ́ lọ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ki ọga ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu to yẹ ko ti fẹyin ti bayii maa baṣẹ lọ fun oṣu mẹta sii.

Aarẹ Buhari ni eyi yoo ṣeranwọ fun iyansipo ọga ọlọpaa tuntun.

Minisita to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa Mohammad Dingyadi lo fidi ọrọ yii fawọn akọroyin nile iṣẹ ijọba niluu Abuja.

Ẹwẹ, Aarẹ Buhari tun fi orukọ awọn olori ileeṣẹ ologun ti wọn ṣẹṣẹ fẹyinti, Abayomi Olonisakin (Rtd ), Lt Gen Tukur Buratai (Rtd), Vice Admiral Ibok-Ete Ibas (Rtd), Air Marshal Sadique Abubakar (Rtd) ati Air Vice Marshal Mohammed S Usman (Rtd), si ile aṣofin agba l'Abuja fun ipo aṣoju Naijiria nilẹ okeere.