Sunday Igboho vs Fulani, Gofundme: ''Ìrọ ní ò, N51.8million kọ́ ní àwọn Naijiria dá fún Sunday Igboho, N4milion ní''

Agbẹnusọ fun Sunday Igboho ti ni lootọ ni awọn ọmọ Naijiria ṣi aṣunwọn owo ''Gofundme'' fun Sunday Igboho; amọ kii ṣe N51.8million.

Eyi ko ṣẹyin iroyin to n ja ranyin nilẹ pe awọn ọmọ Naijiria to wa ni ilẹ okeere ti fi iye to le ni miliọnu mọkanlelaadọta naira sinu asunwọn naa bayii.

Iroyin ni laarin wakati mẹẹdoguin ti wọn ṣi asunwọn naa ni owo yii ti wọ inu rẹ.

Awọn ọmọ Naijiria ti okeere naa n da owo naa lati fi ra ọkọ fun Sunday Igboho lati fi le awọn Fulani darandaran to n pa awọn eniyan kakiri kuro ni ilẹ Yoruba.

Maureen Badejọ to ṣe alagbatẹru rẹ ni awọn ri iye owo to to £9, 450 (N4.8m) laarin wakati mejidinlogun.

Amọ, Ọkan lara awọn ọmọlẹyin Igboho, to ba BBC Yoruba sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ka da orukọ rẹ ni pe iye owo ti wọn ti kojo ko i tii to iye owo ti awọn eniyan n sọ wi pe awọn ri gba,

O fidi ẹ mulẹ pe lootọ ni wọn ṣi apo owo ''Gofundme'' fun Sunday Igboho.

Bakan naa si ni O fikun un pe ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kan ni ilẹ okeere lo gbẹ igbesẹ naa ti wọn si ti ri miliọnu mẹrin naa laarin wakati mẹẹdogun ti wọn ṣi aṣunwọn owo naa.

Laipẹ yii ni Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ gbera lọ si ipinlẹ Ọyọ ati Ogun lati kilọ fawọn Fulani ki wọn so ewe agbejẹ mọwọ bi bẹẹ kọ, wọn o jẹ iyan wọn niṣu.

Wọn ni Sunday Igboho gunlẹ si awọn ipinlẹ yii nigba to lọ sibẹ lati kọju ija sawọn janduku Fulani to n huwa ọdaran nibẹ.

Ohun iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe aarọ ọjọ Aje, ọjọ kinini, oṣu keji ni Igboho fi ilu Ibadan silẹ lọ si ipinlẹ Ogun.

Adari egbe Miyetti Allah ni ile Yoruba, Muhammed Kabir Labar ni nkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Amọ lara awọn Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Sunday Igboho to fi mọ ọmọ gbajugbaja olorin K1,Dami Ayinde Marshal to sọ oko ọrọ si awọn ọmọ Naijiria to n da owo jọ fun Sunday Igboho.