Marriage breakup: Iléẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún méje ká lórí ẹ̀sùn ìfiraẹni-sílẹ̀

Ileẹjọ agbegbe kan ni Kubwa niluu Abuja ti tu igbeyawo ọdun meje ka lori ẹsun ifiraẹni silẹ.

Igbayawo laarin Abubakar ati iyawo rẹ Zainab Ozigi fori sanpọn lẹyin Zainab sọ fun ileẹjọ pe ki wọn tu awọn kan nitori ọkọ oun ti pa oun ti fun ọdun mẹta.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Muhammad Adamu tu igbeyawo ọhun ka amọ o kilọ fun Zainab pe ki o duro fun oṣu mẹta ki o to fẹ ọkọ miiran.

Zainab sọ fun ileẹjọ pe labẹ ofin eṣin musulumi loun ti fẹ Abubakar eyi ti Eledua fi ọmọ kan jinki awọn papọ.

Abubakar naa gba pe ki ileẹjọ tu igbeyawo awọn ka.

Ṣugbọn o ṣalaye pe oun ko fi Zainab silẹ fun ọdun mẹta gẹgẹ bi o ṣe sọ fun ileẹjọ.

''Mo sọ fun iyawo mi pe ki o fi Abuja silẹ wa ba mi nipinlẹ Ogun, ṣugbọn o kọ jalẹ,'' Abubakar ṣalaye.

O ni oun naa ko fẹ ni ajọṣepọ pẹlu Zainab mọ nitori ifẹ oun ti yọ lọkan rẹ.