Celebrity wedding: Wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká tó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2020 yìí

Iyawo dun lọsingin, ọkọ tun mi gbe. Adia fun awọn ilumọọka kan ti wọn ṣe igbeyawo lọdun 2020 yii.

Bo tilẹ jẹ pe, coronavirus ṣe awọn eeyan mọle, iṣede covid-19 ko dena mọ awọn ololufẹ yii lati di tọkọ taya.

Wọnyi ni awọn gbajumọ to ṣe igbeyawo alarede lọdun 2020 yii.

Adewale Adeleke ati Kani Ekanem

Adewale Adeleke ti inagijẹ rẹ n jẹ ''ChairmanHKN'' nin ẹgbọn gbajugbaja olorin takasufe, Davido.

Oun ati Davido jẹ ọmọbibi inu Adedeji Adeleke to lowo bii ṣẹkẹrẹ.

Ninu oṣu keje ọdun 2019 ni Adewale dẹnu ifẹ kọ Kani eyi ti ọmọbinrin naa si ni ko si ṣiṣe ko ṣai ṣe, Adewale loun yoo ba lọ.

Gbogbo iyoku ti di itan bayii, Adewale ati Kani ti di lọkọlaya.

Sandra Ikeji ati Arinze Samuel

Ọjọ kọkanla oṣu kinni ọdun 2020 ni Sandra Ikeji di aya lọọdẹ ọkọ rẹ, Arinze Samuel.

Anita Joseph ati MC Fish

Ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2020 ni Anita Joseph ati MC Fish ṣe igbeyawo niluu Eko.

Kayode Adebayo ati Oluwafunmilayo Adebayo

Ọjọ keje oṣu kẹta ni Kayode Adebayo ṣe igbeyawo ti wọn si di lọkọ laya.

Seilat Adebowale ati Adeyemo Olalekan