You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Tóyìn Abraham kẹ̀yìn sí àgbo títà, Ṣọlá ọmọ Jídé Kòsọ́kọ́ ṣe ọjọ́ ìbí
Bẹbẹ lọ lagbo awọn oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii. Bi ọlọjọ ibi ṣe n ṣe ọjọ ibi ni alayọ n yọ. Idunnu ṣubu layọ fawọn oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii.
Diẹ lara bẹbẹ to lọ niyi.
Tẹni, ọmọ Fẹmi Ọtẹ̀dọla, yoo ba Kunle Afọlayan ṣe sinima
Odu ni Kunle Afọlayan ni ti ka gbe sinima kalẹ ni orilẹede Naijiria ati lagbaye. Ọpọ l o n sọ pe ọrs rẹ ko lee maa ribẹ nitori ogbontagi oṣere ni baba rẹ Adelove, nitori ọmọ ti ẹya ba bi ẹya naa ni yoo jọ.
Nibayii, iroyin to n jade ni pe, 'Citation'sinima tuntun ti Kunle Afọlayan yoo gbe jade laipẹ yoo tun le kenka nitori ọmọ baba olowo nla, Ọtẹdọla, iyẹn Temi yoo farahan ninu sinima naa.
Temi to jẹ abigbẹyin baba olowo Fẹmi Ọtẹdọla yoo ma dara pọ mọ awọn eekan oṣere biiJimi Jean Loius to jẹ ọmọ ilẹ Haiti, Sadiq Daba, Gabriel Afọlayan atawọn miran.
Toyin Abraham ti ileeṣẹ agbo pa
Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham ti ti ileeṣẹ alagbo to ṣi silẹ loṣu kẹwa ọdun 2019 pa.
Toyin ti iroyin sọ pe agbo ibilẹ lo fi bi ọmọ rẹ lẹyin ọpọ ijakadi pẹlu airọmọbi bẹrẹ owo naa loṣu diẹ sẹyin.
Amọṣa funra rẹ lo bọ soju opo ayelujara instagram rẹ lati kede pe, oun ti fi owo agbo naa kọ sibikan naa nitori edeaiyede pẹlu awọn ti wọn jẹ alabadowo pọ rẹ.
Ṣọla Kosọkọ ṣe ọjọ ibi ogoji ọdun
Sọla Kosọkọ, gbajugbaja oṣere, to tun jẹ ọmọ eekan oṣere tiata ni Naijiria, Jide Kosọkọ ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun rẹ. Okiki kan.
Manigbagbe nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa ni eto ikini ku ọjọ ibi ti awọn mọlẹbi rẹ ṣe fun. Lowurọ kutu hai ni awọn mọlẹbi rẹ kaa mọle pẹlu orin, fere, ijo, ẹrin.
Iyalẹnu nla lo jẹ fun Sọla to ni oun ko rokan rẹ rara. Baba rẹ Jide, aburo rẹ Bidemi pẹlu ko gbẹyin nibi ayẹyẹ naa.