You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coffin Business: Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn fẹ́ kó oníṣòwò pósí lọ sí itẹ́ okú
Ijọba apapọ ti pasẹ fun awọn onisowo to yan isẹ posi tita ni aayo, lati tete ko aasa wọn kuro lẹnu ọna ile iwosan apapọ, bibẹẹkọ, wọn yoo ba ara wọn ni itẹ oku.
Awọn alaisan lo n fi ẹjọ sun nipa awọn onisowo posi naa, ti wọn fi abawọle ile iwosan ẹkọsẹ isegun to wa ni olu ilu orilẹede Zambia, Lusaka se isọ wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn alaisan naa ni, bawọn se n fi oju kan awọn posi to wa lẹnu ọna ile iwosan naa, lo n mu ki irẹwẹsi ọkan ba awọn, eyi to nira lati le tete san ninu aisan to n se awọn.
Ilẹ si ti ta si ti awọn eeyan kan, paapa awọn ọdọ ti patẹ posi siwaju ile iwosan naa, lati maa pawo wọle, paapa lasiko yii ti ilu le nilẹ Zambia.
Ibudo posi yii si ni awọn eeyan to ba padanu ẹbi wọn maa n ya lati ra posi, eyi ti ko jinna si ibudo igbokusi ile iwosan naa.
Nibayii, awọn alasẹ ile iwosan ọhun ti wa fun awọn onisowo posi ọhun ni osu mẹta pere lati ko aasa wọn kuro nibudo ti wọn wa yii, bibẹẹkọ, wọn yoo le wọn si itẹ oku to sunmọ tosi lati lọ ta ọja wọn.
Wọn ni asa tita posi niwaju ile iwosan ko ni fun awọn alaisan ni ireti ati ri iwosan, ti yoo si da kun aisan to n se wọn, eyi to lee tete jẹ ki wọn dagbere faye.