You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nkechi Blessing: Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wa dàbí ti Romeo àti Juliet
Ọrọ ifẹ, awamaridi ni, ko si si ẹni to lee mọ ibẹrẹ abi opin rẹ, koda, awọn eeyan miran tun maa n se apejuwe ifẹ bii adanwo.
Bẹẹni ọrọ ifẹ laarin ilumọọka osere tiata lobinrin kan, Nkechi Blessing Sunday, to jẹ ọmọ ẹya Ibo, amọ to n sere ere Yoruba jẹ.
Lasiko to n salaye bi ọrọ ifẹ oun ati ọkọ rẹ, Mike Adeyẹmi se bẹrẹ loju opo Instagram rẹ, lasiko ti wọn n bawọn ololufẹ wọn jẹwọ loju koroju, Nkechi ni ọrọ naa dabi ti Romeo ati Juliet ni.
- Ẹ yé fi ilé, mọ́tò bùga lórí ayélujára - Oshodi-Oke
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Aláàfin yẹ́ Lizzy Anjọrin sí níbi ayẹyẹ ìwúyè rẹ̀
- Lizzy Anjorin yóò jàre Toyin Abraham tó bá jẹ́ pé wọ́n lọ sílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi
- Àwa kìí jà lásìkò tiwa, ta ló bí ẹ tí wàa máa jà? - Iya Rainbow
"Ẹ gbe ẹni wa lati sun sibi kẹ wa gbọ itan bi ifẹ emi ati ọkọ mi se bẹrẹ nitori diẹ ni mo fi han yin nipa mi, ẹ wa ka nipa igbe aye obinrin to yo ifẹ."
Nkechi, ẹni to wa nilẹ Amẹrika bayii lati lọ se afihan sinima rẹ, lo tun lo anfaani irinajo naa lati ri ọkọ rẹ, ẹni to n gbe nilẹ Amẹrika.
Igba akọkọ si ree ti osere tiata naa yoo sisọ loju ololufẹ rẹ ọhun, Michael, ti gbogbo eeyan ms si Razor Ray, ti oun naa jẹ osere tiata to fi orilẹede Amẹrika se ibujoko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló ń fa ìdádúró nípa ìfilọ́lẹ̀ ‘Amotekun’ tó yẹ kò wáyé lónìí?
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀ kọ ipò wọn sílẹ̀ ní ìran ọba
- Ta ló ń fi ògùn Paracetamol, Hypo dín Gààrí lọ́dọ̀ yín níbẹ̀ yẹn?
- Makinde fẹ́ san ₦30,000 fáwọn òṣìṣẹ́ l’Oyo, yóò tún kọ́ ọjà ìgbàlódé sí Akẹ̀sán
Nkechi ni ifẹ awọn mejeeji bẹrẹ ni kete ti awọn fi oju kan ara awọn, to si ti n gbinlẹ si lati igba naa wa.
Mike adeyẹmi, nigba ti oun naa da si ọrs ọhun ni "inu agbekalẹ sinima mi kan, ti mo pe akọle rẹ ni 'Bad Market' ni a ti kọkọ pade, bi o tilẹ jẹ pe a foju kanra fun igba akọkọ lasiko ta lọ pade rẹ ni ibudokọ reluwe, ti ifẹ si ru bo wa loju lọgan."
"Ninu sinima naa, a jẹ ete ara wa, bi ifẹ wa si se bẹrẹ ree. Aaro rẹ maa n sọ mi gidigidi nitori ọdun 2018 ni a ti foju kan gbẹyin, inu mi si dun lati gbaa ni alejo lẹẹkan si lorilẹede Amẹrika."
A jẹ wipe ko si ibi ti ifẹ kii ti gbilẹ, a ki Michael Adeyemi ati Nkechi Blessing pe wọn ku oju to tun tura ri.