JAMB ṣe ìdádúró lílo nọ́mbà ìdánimọ̀ fún ìdánwò àṣewọlé ọdún 2020

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ to n ri si idanwo aṣewọle iwe giga, JAMB ti ṣe idaduro lilo nọmba idanimọ Naijiria, NIN, fun iforukọ silẹ idanwo aṣewọle ọdun 2020.

Ọga agba ajọ JAMB, Ishaq Oloyede lo fi ọrọ naa lede nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l'Abuja.

Bakan naa ni ajọ ọhun fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ, nibi to ti dari awọn oluṣedanwo lati fi orukọ wọn ranṣẹ si 55019 fun iforukọ silẹ idanwo naa.

Ishaq sọ pe, idaduro lilo nọmba idanimọ naa jẹ ọna lati fun awọn to n ṣe idanwo JAMB lanfaani sii, lati lee gba nọmba idanimọ wọn.

O ni igbesẹ naa tun jẹ ọna lati lee wa ojutu si awọn kudiẹkudiẹ to n waye ni awọn ojuko idanwo JAMB kaakiri oriliẹ-ede yii.

Ọga agba ọhun ṣalaye siwaju sii pe, awọn oluṣedanwo ko nilo nọmba idanimọ fun idanwo ọdun 2020, ṣugbọn wọn yoo nilo nọmba naa fun idanwo ọdun 2021.

Ṣaaju lọdun 2019 ni ajọ JAMB sọ pe awọn to ba fẹ ṣe idanwo aṣewọle ọdun yii yoo nilo nọmba idanimọ naa lati lee fopin si bi awọn kan ṣe ma n forukọ silẹ funn idanwo ọhun ju igba kan lọ.