You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Human traffiking: Òyìnbó kòráà, amòfin kan wọ gbaga òfin fún títa obìnrin kan sóko ẹrú
Ọwọ ofin ti tẹ ọmọ orilẹede Lẹbanon kan torukọ rẹ jẹ Wasit Muhammad pẹlu awọn eeyan meji miran ti wọn lo lọwọ ninu tita arabinrin kan, torukọ rẹ n jẹ Ọmọlọla Ajayi si oko ẹru ni orilẹede Lebanon.
Fidio kan ti arabinrin Ajayi Ọmọlọla fi sita laipẹ yii lo di alatagba lori ayelujara nibi ti o ti n ṣalaye pẹlu omije loju pe, awọn eeyan kan ta oun si orilẹ-ede naa labẹ pe oun yoo ri iṣẹ aje se.
Amọ o ni ọrọ ọhun yi pada nigba ti oun de ọhun nitori nibẹ ni o ti lu si oun leti pe, wọn ti gba owo oku ati aye oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìlẹ̀kẹ̀ ìdí mi ló kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn afipábánilòpọ̀ ní Lebanon
- Kí ló ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí?
- Ẹ́ kéde iye ọlọ́pá tó gba rìbá, kẹ tó máa yin ara yín - Aráàlú sọ fún ọlọ́pàá
- Ẹ wo ìgbà mẹ́jọ tí wọ́n fi àdó olóró já bàálù akérò lulẹ̀ bíì ti ìṣẹ̀lẹ̀ Iran
- Ìjọba Ondo, inú fìfo la fi ń ṣiṣẹ́, ẹ ṣan ọ̀pọ̀ owó oṣù tẹ jẹ wa - Àwọn dókítà fárígá
- Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀
Ọlatunji Sanusi to jẹ agbẹjọro ati ẹlomiran ti orukọ rẹ n jẹ Tunde, ni awọn meji ti ọwọ ba pẹlu Oyinbo koraa naa.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, iwadii ileeṣẹ abo ara ẹni labo ilu fi kun un pe, yatọ si arabinrin Ajayi, eeyan mejidinlọgbọn ni awọn eeyan mẹta yii ti ran lọ soko ẹru loke okun labẹ pe wọn fẹ lọ ṣiṣẹ kore oko dele.
Fidio alaye ti arabinrin Ọmọlọla se ree, eyi to gba ori ayelujara kan:
Ninu atẹjade kan ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq fi sita, ijọba ipinlẹ Kwara ni oun ko ni gba iwa bẹẹ laaye mọ rara.
Ẹtan pe yoo lọ di olukọ ede oyinbo ni wọn fi mu Ọmọlọla Ajayi lọ sorilẹ-ede Lẹbanon, ki ọrọ to di baa mii nigba to de ibẹ tan.