Iran war: Wọ́n ti mu aṣojú ọmọ Britikó ní orílẹ̀-èdè Iran

Bi awọn eniyan Iran ṣe n ṣe iwọde lodi si aṣiṣe ti awọn adari wọn ṣelori ọkọ ofurufu to jabọ naa ni wọn ti mu aṣoju ile Gẹẹsi kan Àwọn ọmọ Iran yarí mọ́ ìjọba lọ́wọ́ lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ọ jíjá bàálù Ukrain lulẹ̀

Rob Macaire ni wọn mu fun wakati mẹta ni ilẹ Iran to jẹ ọmọ United Kingdom lori ofin agbaye.

Iroyin ni Ogbẹni Macaire n gbadura fawọn toku ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu ni lasiko ti wọn n yinbọn naa to pada di iwọde ni Tehran.

Wọn ni lasiko ti Rob n pada lọ si ile ilẹ Gẹẹsi to tun jẹ ẹmbasi ilẹ Gẹẹsi ni Tehran to jẹ olu ilu Iran ni wọn deede gbee.

Ṣaaju ni adari Iran ni awọn yoo ṣe iwadii ohun to ja ọkọ ofurufu naa bọ ki wọn to tun ni awọn ọmọ ogun Iran lo ṣeeṣi ja ọkọ naa bọ.

Ọkọ ofurufu ilẹ Ukraine naa ni awọn eniyan mọkan dinlọgọsan an inu rẹ di ero ọrun pẹlu awọn oṣiṣẹ inu rẹ.

Ni kete ti ileeṣẹ iroyin ilẹ Iran, Tasnim kede pe wọn ti mu aṣoju ilẹ̀ Gẹẹsi naa ni ile iṣẹ iwe iroyin Etemad na fi fọto aṣoju naa si ori ikanni twitter rẹ

Akọwe agba fun ileeṣẹ ilẹ Gẹṣi to n ri si ajọṣepọ lagbaye, Dominic Raab ti fi atẹjade sita.

Ninu atẹjade naa lo ti ni mimu aṣoju ile Gẹẹsi ni Tehran ṣe lodi si aṣẹ ati ofin ajọṣepọ ni agbaye.

Dominic ni o ti hande pe Iran fẹ maa fa jọgọ ti ilẹ UK ko dẹ ni gba fun wọn.