You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Hanan Buhari: Ìjọba ní Ọmọ Buhari lásẹ láti wọ bàálú Nigeria Air force
Orisirisi awuye lo ti ṣẹyọ lẹyin ti abigbẹyin Aarẹ Buhari, Hanan Buhari wọ ọkọ ofurufu, Nigeria Air Force lati lọ ṣe iṣẹ ọwọ rẹ.
Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbeṣẹ naa wi pe arabinrin naa n lo baalu ti awọn ara ilu n san owo ori lẹ lori lati lọ fi sẹ iṣẹ ara rẹ ni ipinlẹ Bauchi ni àwọn miran ni ko buru
Ayẹyẹ ọdun Durbar ni Bauchi ni ọmọ aarẹ Buhari lọ ya fọto rẹ gẹgẹ bi iṣẹ aje rẹ nibi to ti ni anfani lati ya aworan nipa ọdun naa ati awọn nkan miran ni Bauchi.
- Amotekun kò ní gbé ìbọn o! kíni wọn yóò máa ṣe ní ìpínlẹ̀ - DAWN Commission
- Àwọn ọmọ Iran yarí mọ́ ìjọba lọ́wọ́ lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ pé òun ló já bàálù Ukrain lulẹ̀
- Wo Sultan Qaboos bin Said, ẹni tó gbàkóso ìgbé ayé òṣèlú Oman fún àádọta ọdún
- Ẹ kò nílò nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN fún ìdánwò àṣewọlé ọdún 2020 - JAMB
Amọ, ijọba lasiko ti wọn n fesi si igbeṣẹ naa ni ọmọbinrin naa ni Hanan ni aṣẹ labẹ ofin lati lo ọkọ ofurufu naa gẹgẹ bi ọmọ Aarẹ orilẹ-ede Naijiria.
Olubadamọran pataki fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu lọ sọ bẹẹ pe nitori o gba aṣẹ lọwọ Baba rẹ ni o fi lo ọkọ ofurufu naa.
Garba Shehu ni labẹ ofin, eniyan mẹrin lo laṣẹ lati lo ọkọ ofurufu ijọba Naijiria, iyẹn ni Aarẹ, Awọn ẹbi aarẹ, igbakeji Aarẹ ati Aarẹ Ilẹ Igbimọ Asofin agba ati kekere orilẹ-ede Naijiria ati ẹnikẹni ti Aarẹ ba gba laaye pẹlu aṣẹ.
Bẹẹ, lo tun fikun un pe Aarẹ Buhari sọ fun olubadamọran lori eto aabo orilẹ-ede Naijiria lori bi arabinrin naa ti lọ ṣe iṣẹ ayawòrán ni ayẹyẹ Durban to waye ni Bauchi.
Ọmọbinrin Aarẹ Buhari naa lo gba iṣẹ ati lọ ya fọtọ ni ayẹyẹ naa, lẹyin to gba ipo oni ipele kini (First Class) ninu ẹkọ imọ ayaworan lati Fasiti Ilẹ Gẹẹsi laipẹ yii.
Amọ awọn ọmọ Naijiria ati ẹgbẹ oṣelu PDP ko fi ara irẹ gba ọrọ yii, ti wọn si fikun un wi pe owo goboi ni ijọba n gba lọwọ araalu lati tun awọn ọkọ ofurufu yii ṣẹ.
Wọn tilẹ ran ijọba leti wi pe ko ranti ipinnu rẹ lati ta awọn ọkọ baalu yii, ki ijọba le e ri owo fi pese awọn ohun amayedẹrun fun ijọba.
PDP ni ṣe o yẹ ki ọmọ aarẹ maa gun ọkọ ofurufu ijọba nigba ti eyi ti igbakeji aarẹ n gun n dẹnukọlẹ lojoojumọ?
Awọn miran sọ ootọ ọrọ funra wọn lati tubọ tẹ ipa mọ iṣẹ aje wọn bayii ti ọmọ aarẹ ba le maa ya aworan kiri.
Bẹẹ ni wọn fikun un pe, iye owo to le ni biliọnu, N8.5bn ti ijọba pinnu lati na ninu eto isuna ọdun 2020 ti pọ ju fun itọju baalu ọkọ ijọba.
- Ilẹ̀ UAE ti n fún àwọn arìnrìnàjò ní ìwé ìrìnnà ọlọ́dún márùn ún
- Siasia bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ N100m lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn án
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Pósí tí wọn ń tà lẹ́nu ọ̀nà ilé ìwòsàn àpàpọ̀ ló ń tètè pa wá - Aláìsàn figbeta