King of Bahrain robot bodyguard: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ‘rọ́bọ́ọ̀tì Ọba Bahrain’

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni fidio kan gba ori ayelujara kan, eyi to sọ pe Ọba orilẹ-ede Bahrain ṣabẹwo si Dubai pẹlu rọbọọti kan to jẹ ẹṣọ alaabo rẹ.
Akọle fidio ọhun sọ pe "Ọba Bahrain, Hamad bin Isa Al Khalifa wọ orilẹ-ede Dubai pẹlu rọọbi to fi n ṣe ẹṣọ."
Akọle miran ni, ẹṣọ naa ni ẹrọ ayaworan ọọdunrun le lọgọta lara, to si le e sọ ede mẹfa ọtọọtọ, bẹẹ lo tun ni ibọn ilewọ.
Koda, awọn iroyin kan sọ pe, o ni ohun ija to pọ lara to bẹẹ to fi le e ba ẹgbẹrun le aadọta eeyan ja, ṣugbọn ko si ootọ ninu iroyin naa rara.
Ohun ti a mọ nipa fidio naa ree:
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2019 ni wọn fi fidio naa si ori ikanni YouTube, pẹlu akọle pe "rọbọọti to ga ni iwọn ẹṣẹ bata mẹjọ ki awọn eeyan ni UAE."

Oríṣun àwòrán, YouTube Screeshot/ Dubai17
Ninu fidio ọhun ni rọbọọti naa, ti orukọ rẹ n jẹ Titan, ti ki awọn eeyan, to si tun darukọ ara rẹ ni ilu Abu Dhabi.
Lara awọn ileeṣẹ iroyin to lami laaka to ti gbe iroyin nipa rọbọọti ọhun jade lọdun 2019 ni Khaleeji Times ati Gulf News.
Ṣaaju asiko naa, rọbọọti ọhun lọ si ipade ita gbangba awọn to n ri si eto abo ni Abu Dhabi ni oṣu Kẹta ọdun 2018.
Ki ni wọn n fi rọbọọti naa ṣe?
Titan ni rọbọọti akọkọ lagbaye ti wọn fi n da awọn eeyan laraya, ileeṣẹ Cyberstein Robots, nilẹ Gẹẹsi lo si ṣe e.
O ga ni iwọn ẹsẹ bata mẹjọ, oju rẹ si da bii agbari, koda awọn eeyan kan n fi ṣapejuwe rọbọọti Transformer to wa ninu sinima agbelewo kan.

Oríṣun àwòrán, YouTube Screeshot/ Dubai17
Titan ti da awọn eeyan laraya ni oniruru awọn ayẹyẹ kaakiri, bii ere idaraya agbaye Commonwealth.
Ohun pato ti wọn ṣe rọbọọti ọhun fun, ni ko maa da awọn eeyan laraya lodi si iroyin to gbode pe, ẹṣọ alabo Ọba Bahrain lo ni, ati pe o ni ohun ija ogun lara.













