Lagos Building Collapse: Èèyàn méjì tó há sábẹ́ ilé tó wó ní Ebute Meta ti ń gba ìtọ́jú, LASEMA ń ṣàyẹ̀wò ilé náà ló̩wọ́

Ebute meta

Oríṣun àwòrán, Said

Ile kan to wa ni ọgangan Ileewosan Comprehensive Health Centre ni agbegbe Ebute Meta nipinlẹ Eko la gbọ pe o ti ṣaa dede wo lulẹ funrarẹ ti eeyan meji si ha sabẹ ile naa.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA sọ pe arugbo kan ati ọmọbinrin to ha sabẹ ile naa fara pa diẹ ṣugbọn wọn ri wọn doola ti wọn si ti kọkọ n tọju wọn ninu ọkọ ilera to n jẹ LASAMBUS.

Ile to wo yii ti pe ọdun mẹẹdọgbọn, o wa ni nọmba 95, agbegbe Cemetry Street, lopopona Eko si Abeokuta ni Ebute Metta.

Awọn olugbe agbegbe atawọn to n gbe inu ile naa sọ pe o ti n fi ami han pe agara ti da a fun igba diẹ.

Ebute meta

Oríṣun àwòrán, Said

Ẹwẹ, iwadii ti ajọ LASEMA ṣe lori ile naa fi han pe alaja mẹta ni ti o si ni ojule mẹfa oni yara kan, palọ kan to si kun fọfọ pẹlu awọn to gba a lẹyin ti atunlekọ kan ti idile kan gba tun un kọ.

Nibayii, wọn ko tii mọ idi pato to fa ile wiwo naa. Amọ awọn oṣiṣẹ pajawirii ajọ LASEMA atawọn nkan mii fun eto ilera ti wọn gbe lọ sibẹ.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke