Amotekun: Fídíò ìfilọ́ọ̀lẹ̀ "Amotekun" rèé pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìgboya látẹ́nu àwọn gómìnà Yorùbá

Àkọlé fídíò, 'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Nibi akanṣe eto ifilọlẹ ikọ alaabo Amotẹkun to waye nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo, awọn gomina ilẹ yoruba mẹnu ba awọn ohun to ṣe koko nipa ikọ naa.

Gomina ipinlẹ Ondo ti o tun jẹ alaga agbarijọpọ awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu ni ifilọlẹ Amọtẹkun jẹ nnkan ayọ fun gbogbo awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Ifilọọlẹ Amotẹkun

Gomina Kayode Fayemi ti ipinlẹ Ekiti ni eto aabo ilẹ Yoruba ṣe pataki si awọn gomina, eyi lo si ṣe atiwaye ifilọlẹ Amọtẹkun.

O ni Amọtẹkun ko waye lati rọpo awọn ileeṣẹ aabo to n bẹ nilẹ tẹlẹ, ṣugbọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo to ku, ki eto naa le kẹsẹjari.

Ifilọọlẹ Amotẹkun
Ifilọọlẹ Amotẹkun

Ọọni Enitan Ogunwusi sọ ọ̀rọ̀ idupẹ pe "Ẹ bá mi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn gómìnà mẹ́fẹ̀fà yìí fún agbekalẹ Amotekun".