Brain Squad: Àwọn ọmọdébìnrin Nàìjíríà ṣe "App" ìrànwọ́ owó iléèwè

Àkọlé fídíò, Brain Squad: Àwọn ọmọdébìnrin Nàìjíríà ṣe "App" ìrànwọ́ owó iléèwè

Brain Squad jẹ ẹgbẹ awọn ọmọdebinrin ọmọ Naijiria marun kan ti wọn ṣe agbejade ẹrọ kan ti o le ran awọn ọmọ ileewe to ba ku diẹ kaato fun lati ṣetọju ara wọn nileewe.

Eto iranwọ ori ayelujara yii bẹrẹ latori owo ileewe, bata ati aṣọ ileewe, itọju ara nile iwosan.

Ẹrọ to n ṣeranwọ owo ileewe

Awọn ọmọdebinrin naa da ẹrọ ori kọmputa ti wọn pe ni "Handsout" jade

Wọn ti jawe olubori fun Naijiria ni ipele ti ilẹ Afirika nikan wọn yoo si tun lọ ṣoju ikọ Afirika lagbaye.

Ẹrọ to n ṣeranwọ owo ileewe

"App" naa ti gba ami ẹyẹ People's Choice lọdun yii ni Sillicon Valley, ilu Carlifornia nibi ti o le ni ẹgbẹrun mọkandinlogun awọn amugbalẹgbẹ ọdọ ti lọ ṣafihan ohun ti wọn fi ọgbọn ori ṣe.

"App Handsout" yii yoo fun gbogbo eniyan lagbaye lanfani ati nawọ iranwọ pẹlu irọrun si awọn ọmọde Naijiria ati idile wọn ki wọn le san owo ileewe, ohun ikawe ati fun ilera wọn.

Ayomikun, Ivana, Muna,