Sex For Grade: Ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún láì sí owó ìtanràn ni ìjìyà olùkọ́ oníwà ìbàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Gettty
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfín àpapọ̀ tí gba àbá kan wọle to wa fun ìjìyà ẹni to bá fí ìbálòpọ̀ lọ obìnrin ni tipátipá tí wọn pé ni (Sexual Harassment in Tertiary Educational Institutions Prohibition Bill, 2016).
Gẹ́gẹ́ bi aṣòfin àgbà Ovie Omo-Agege tó ṣe àgbátẹru rẹ ṣe sọ, àbádofin náà yóò jẹ ki àwọn amokun ṣèkà tó fẹ́ràn láti ma fi ìbálòpọ̀ lọ akẹ́kọ̀ọ́ fún máàkì, kọ ẹ̀kọ́ nla.
- Ìdájọ́ àkọ́kọ́ kò tẹ́ mi lọ́rùn, mo tún tí gbé Seyi Makinde lọ silé ẹjọ́ - Bayo Adelabu
- Kí ló mú kí Adájọ yin ìbọn lu ará rẹ láyà nílé ẹjọ́?
- Efunjoke Coker: Abiyamọ́ tó ṣé atọna àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Queens College
- Gbèsè niye èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá- Emir Sanusi
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
Ta ni òfin to n tako ibalopọ lọna aitọ lè è mú ?
- Ẹnikéni to ba wà ní ipò àṣẹ, bií ajọsepọ láàrin olùkọ àti akẹ́kọ̀ọ́.
- Olùkọ tó ń síṣẹ náà ni sàn-sàn tàbi èyí to kan fi n pawọdà nílé ẹko gíga kan
- Olùkọ tó n kọ àkẹkọ̀ọ́ níwèé, tó ń ba mojúto iwé àrokọ àláṣe kágbà, tàbí to jẹ olùtọ́sọna fún àkẹkọ̀ọ́ ní ilé ẹkọ gíga
- Olukọ ti àkẹ́kọ̀ọ́ ba gbọ́kan lé tabi tí ìgbéṣẹ olùkọ bẹẹ lee nipa lórí ẹkọ́ irufẹ akẹkọ bẹẹ.
Asìkò wo ní ẹ̀sùn títami oge lọ́nà àítọ̀ lè jẹyọ ?
- Olukọ to ba ba akẹkọọ tami oge lọnà àìtọ tàbi to ni ìbálopọ̀ pẹlú akẹ́kọ̀ọ́ ti ko ti to ẹni ọdun méjidinlogun tàbi ẹni to ni ìpeníjà ọpọlọ
- Olukọ tó bá bèèrè fún ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọọ́ tàbi ẹni to fẹ́ di akẹ́kọ̀ọ́, kí o ba le ràn-an lọ́wọ́ ninu ẹkọ rẹ̀, lati fún ni àmì ẹ̀yẹ tàbi ṣeranwọ owó fún akẹ́kọ̀ọ́ naa
- Ẹni to mọọmọ fọ́wọ́ra àkẹkọ̀ọ́ lára, dàámú akẹkọ lọ́nà àìtọ́, fọ́wọ́kan tàbi kí o fàá lọ́mú nitori olùkọ́ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fọ́wọ́kan ọmu, ètè, itan, ìdí àti gbogbo ibi to yẹ ki eniyan dààbo bò lára obinrin
- Olùkọ́ kò lẹtọ láti fi fọ́tọ̀ ìhòòhò tàbi fọ́nran ìbálopọ̀ tàbi ohunkohun to farapẹ kọlọfin ara akẹkọ ranṣẹ sita
- Nígbà ti ìgbésẹ̀ olùkọ náà ba ti n mú ìdukoko mọni lọ́wọ́, tàbi ti olùkọ bá n sọ̀rọ̀ láti rí akẹkọ̀ọ́ mu
Ijiya to wa fun olukọ to ba beere ibalopọ lọwọ akẹkọ lna aitọ:
Abadofin náà fí kun pé ẹnikẹni to ba lùgbàdi gbogbo àwọn ẹsun yìí yóò lọ sẹ́wọ̀n ọdún márun gbáko tàbi ẹwọn ti ko din ní ọdún mejì láì si ore-ọ̀fẹ́ oniduro tabi sisan owo itanran.

Oríṣun àwòrán, NASS
Akẹkọọ lee gbe awọn igbesẹ yii ti olukọ rẹ ba dẹnu ifẹ kọ ọ:
Nígbà kigba tí ìrú ǹkan báyìí ba wáye, tí ẹnikẹni fi ìbálopọ lọ akẹ́kọ̀ọ́, àkẹ́kọ̀ọ́ ni ẹtọ́ láti lọ fi ẹjọ́ sùn ni àgọ́ ọlọ́pàá tàbi àgbẹjọrò àgbà ní ipinlẹ fún ẹ̀sún ìwà ọdaràn.
Akẹ́kọ̀ọ́ náà tún lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé olùkọ̀ọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe n ṣe ń sẹjọ tókù, pẹ̀lú ẹ̀rí tó dáju.

Oríṣun àwòrán, NASS
Kílode ti ofin yii ko se tii jẹ lilo?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún 2016 ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ti ka àbádofin yíì de ipele kẹta, síbẹ̀ kò tii rí ìmọ́lẹ láti di ofin.
Idi ni pe ààrẹ Muhammadu Buhari ko tii buwọ́lu àbádofin náà titi di akoko ti BBC gbe fidio jade lori iwa ibajẹ ọhun.












