Fayemi: Ìdápadà iléèwé Christ School fún ìjọ Anglican tó dá a sílẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí ìpolongo ìbò

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Ijọba ipinlẹ Ekiti da ileewe Christ School, Ado Ekiti pada fun ijọ Anglican to da ileewe naa silẹ.
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ni imuṣẹ ara awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo ibo ni ọdun to kọja lati da awọn ileewe pada fun awọn to ni wọn.
- Èèyàn kan tún jáláìsí nínú ìjàǹbá ọkọ̀ lọ́nà márosẹ̀ Ibadan sí Eko
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
- Èèyàn mẹ́ta kú nígbà tí ọkọ̀ bọ́ọ̀sì jábọ́ sí ódò Ọ̀ṣun
- Ìkọlù ibùdó epo rọ̀bì Saudi Arabia yóò kóbá jíjẹ-mímu àwọn èèyàn rẹ̀ - Buhari
- APC, ẹ gbé òṣèlú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ná, kẹ padà wá lọ́dún 2022 - Ṣèyí Mákindé
- Lizzy Anjorin fèsì padà, ó ní ìsọ̀ alágbo ni Toyin Abraham bímọ sí, kìí ṣe London
Gomina Kayọde Fayẹmi ti oun pẹlu jẹ akẹkọjade ileewe Christ school Ado Ekiti ni erongba igbesẹ naa ni lati lo idapada naa gẹgẹ bii ọpakutẹlẹ fun dida awọn ileewe yooku pada fun awọn to ni wọn.
Biṣọọbu ijọ Anglican ni ipinlẹ Ekiti Ẹniọwọ Christopher Ọmọtunde lo tẹwọ gba iwe idapada ileewe naa lọwọ gomina Fayẹmi.
Amọṣa bi inu awọn akẹkọjade kan ṣe n dun si iṣẹlẹ ọhun ni awọn miran n kọrun ẹsọ pẹlẹ nitori ilẹ n yọ.
Oloye Faṣohun to jẹ akẹkọjade ileewe Christ school Ado ekiti ti o tun ti figbakan ri jẹ alaga igbimọ alakoso ileewe naa ṣalaye pe ifasẹyin nla gbaa ni igbesẹ naa yoo mu ba ọla ileewe girama naa to ti roke fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Alagba Faṣohun ni ko si ipenija kan to kọja agbara ileewe naa tabi ijsba to n gbọ bukata rẹ ni lọwọlọwọ to lee ṣokunfa ki wọn faa le ijọ Anglican pada.
O ni ara awọn ipalara ti igbesẹ naa yoo ṣe fun ileewe naa ni idaduro idagbasoke fun awọn olukọ eleyi to ni yoo le ọpọ oluks to dantọ kuro nibẹ ti yoo si faye gba awọn gbantuẹyọ.
Bakan naa lo ni eyi yoo tumọ si alekun owo ileewe ti awọn akẹkọọ yoo maa san nibẹ. Oloye Faṣohun ni eleyii yoo mu ki adinku ba iye awọn akẹkọọ ti o n wa si ileewe naa.
Amọṣa ninu ọrs tirẹ, Biṣọọbu ijọ Anglican ni ẹkun Ekiti oke, Ẹniọwọ Olubọwale ṣalaye pe ijiroro yoo waye laarin awọn Biṣọọbu ẹkun mẹta to wa ni ipinlẹ Ekiti, lori ọna ti wọn yoo gba lati mu ọjọ ọla rere bọ fun ileewe girama naa












