Osun Accident: Agbegbe Gádà ní ìlú Ẹdẹ ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eeyan mẹta lo jade laye lalẹ ọjọ aiku ni ilu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun nigba ti ọkọ bọọsi ti wọn wa ninu rẹ, jabọ sinu odo Ọṣun ni agbegbe Oke-gada ni ilu Ẹdẹ.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni aisi ikọ adoola ẹmi lasiko, lo ṣokunfa iku awọn eeyan naa.
Bakan naa, ni awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn salaye pe ohun jijẹ lo kun inu ọkọ naa lasiko ti o fi re bọ sinu odo naa.
- APC, ẹ gbé òṣèlú tì sẹ́gbẹ̀ kan ná, kẹ padà wá lọ́dún 2022 - Ṣèyí Mákindé
- Lizzy Anjorin fèsì padà, ó ní ìsọ̀ alágbo ni Toyin Abraham bímọ sí, kìí ṣe London
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
- Ìkọlù ibùdó epo rọ̀bì Saudi Arabia yóò kóbá jíjẹ-mímu àwọn èèyàn rẹ̀ - Buhari
- South Africa bẹ Naijiria lórí ìsekúpani nítorí ẹ̀yà!
Nnkan bi agogo meje alẹ ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awakọ bọọsi naa n gbiyanju lati yẹra fun awọn koto to wa kaakiri oju popo naa.
Amọṣa, wọn ni ko si iranwọ lati doola ẹmi wọn titi di nnkan bii agogo mọkanla alẹ, afi igba ti awọn eeyan kan fi dide lati doola wọn.
Sugbọn dokita ileewosan ti wọn gbe wọn lọ ni oku ni wọn gbe wọn wọ ileewosan naa.








