You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Xenophobic: O lè ní ẹgbẹ́ta àwọn ọmọ Naijiria tí wọ́n ti ṣetàn láti padà sílé!
Aṣoju ilẹ Naijiria lorilẹ-ede South Africa, Adama Godwin kede awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti ṣetan lati pada sile lẹyin ikọlu.
Adama ni o ti le ni ẹgbẹ́ta àwọn ọmọ Naijiria tí wọ́n ti ṣetàn láti padà sílé ninu orukọ ti awọn ti ni akọsilẹ rẹ bayii.
Ikọlu to n waye lorilẹ-ede South Africa lodi si awọn alejo ni eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti sọnu ninu rẹ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyinÌjọba South Africa pèpàdé lórí ìkórìíra àlejò.
- Xenophobic Attack: Àwọn ọmọ Nàìjírìá bínú kọlu Shoprite l'Eko
- Xenophobic Attack: 'Nàìjíríà ló máa forí kó kíkọlu iléeṣẹ́ South Africa jùlọ'
- Àwọn ọmọ Naijiria kóju ija sí àwọn South Africa wọ́n ní "Ó tó gẹ́"
- ShopRite Ibadan gbé ìlẹ̀kùn tìpa torí ìkọlù àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn
- Àwọn òṣèré tíátà takò ìkọlù South Africa àti ìgbẹ̀san ọmọ Nàíjíríà
Adamu ni titi di asiko yii, awọn ko tii le sọ ni pato odiwọn iye ọmọ Naijiria to ṣetan lati pada sile.
O ni awon ṣi n ṣeto iforukọ silẹ titi di asiko yii ti BBC fi n ba wọn sọrọ.
O ni ọkọ ofurufu Air Paeace meji ti wa nilẹ lati bẹrẹ igbesẹ gbigbe awọn eniyan pada sile lalaafia kuro ni orilẹ-ede South Africa.
Adamu Godwin to n dari dida awọn ọmọ Naijiria pada sile lati South Africa ni lọjọ ruu ni awọn ikọ akọkọ a pada si Naijiria kuro ni South Africa.
O ni awọn ko tii da gbendeke igba ti wọn yoo dẹkun dida awọn eniyan pada sile.
Adamu ni ti awọn ti o ba fifẹ han lati lọ sile ba ṣi n pọ nile ni ijọba yoo maa gbe igbesẹ lati gbe wọn wa sile.
Irufẹ Awọn ọmọ Naijiria wo lo n pada sile?
Nigba ti BBC beere lọwọ Aṣoju Naijiria ni South Africa irufẹ awọn eeyan ti wọn n da pada sile lọwọ rẹ, O ni ọpọ ninu wọn jẹ awọn ti ikọlu naa ti ba okowo wọn jẹ.
O ni awọn ti ikọlu Xenophobia to lodi si alejo naa ti jo ọja wọn ti okowo wọn si ti di nkan miran.
Bakan naa ni Adamu ni awọn maa da awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa ni ibudo dida ajeji pada ti ko ba ni iwe igbelu to yẹ lọwọ (Deportation Camps).
O ni ko si awọn ti wọn wa ni ẹwọn ni South Africa ninu awọn ti ijọba n gbero lati da pada sile lasiko yii.
Ni afikun, Adamu ṣalaye fun BBC pe ijọba Naijiria ti n ṣe akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ji ọja tabi okowo wọn ko ni Johannesburg.
O ni ti awọn ba pari iforukọsilẹ awọn ti ọrọ kan ati odiwọn ọja wọn ti ikọlu yii bajẹ ni wọn yoo to mọ igbesẹ to kan ni gbigbe.