You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní Ikorodu
Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹsan an ni agbegbe Imọta ni Ikorodu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana ṣalaye pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ti wọn jẹ aṣiwaju ninu ẹgbẹ koowa wọn ni wọn ti sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ si awọn eeyan agbegbe Ikorodu lọrun.
Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣe sọ, o ni agogo mẹsan an alẹ ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan an, ọdun 2019 ni awọn kan ta ọlọpaa lolobo nipa wọn.
Elkana ni pe wọn kẹẹfin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ọlọpaa ti n wa fun igba pipẹ lagbegbe ilu Igbalu.
Ni eyi ti awọn dide si lẹyẹ o ṣọka ti wọn si ni ikọ kogberegbe "Operation Crush" ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹkọleti lọ si agbegbe naa.
Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ba lọwọ wọn ni aake, ọbẹ ati fila bẹntigọọ to jẹ ti ẹgbẹ okunkun iyẹ.
Emmanuel Chinonso to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun àti Thomas Isreal to jẹ ọmọ ogun ọdun ni wọn kọkọ mu bi afurasi.
Lara awọn nkan ija oloro ti wọn gba lọwọ wọn ni aake meji, ada ati fila ti o jẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkunu ẹyẹ.
Lẹyin eyi ni awọn mejeeji jẹwọ pe awọn wa lara adari ẹgbẹ okunkun to n ṣọṣẹ ni agbegbe Imọta ki isẹ iwadii awọn agbofinro to ṣafihan awọn meje miran.
Awọn meje yii ni: Ariyo Omonuga to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn; Oyerinde Omoniyi to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun; Adelaja Opeyemi to jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn; Hassan Babatunde to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn; Sodiq Babatunde to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun; Sodiq Oladire to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun ati Shakiru Liasu ti oun jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun.