Ekiti state: Nítoríi fóònù ìbánisọ̀rọ̀, géńdé méjì kú sínú u kọ̀ǹga l'Ékìtì

Ibanujẹ dori agba kodo, bẹẹni awọn ọmọ wẹwẹ ko si lẹnu ọmu ni ileto Anaye nijọba ibilẹ Emure Ekiti bayii nigba ti awọn gende meji jabọ sinu kọnga kan nibẹ ti wọn si dagbere f'aye.

Awọn mejeeji ọhun, ti wọn pe orukọ wọn ni Foluṣọ Ajayi, Vosco pẹlu ọdọmọdekunrin kan ti inagijẹ rẹ n jẹ Alhaji ni wọn gba fun iṣẹ agbaṣe kan ni ileto ọhun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọkan ninu awọn mejeeji yii gbiyanju lati yọ ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ to jabọ sinu kọnga yii lasiko to fi n pọn omi lati fi jẹun lo ba di wọ ninu kọnga.

Iroyin ni foonu Vosco lo jabọ si kanga nigba to n fa omi lọwọ, lasiko igbiyanju rẹ lati yọ foonu naa lo ba rebọ.

Ni Alhaji ọrẹ rẹ naa ba fẹ sare ran an lọwọ ni oun naa ba ko si kọnga.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ṣalaye pe ni kete ti ọkunrin akọkọ jabọ sinu omi ni ẹnikeji rẹ gbiyanju lati yọọ jade ni oun pẹlu jabọ sinu kọnga naa to si ku.

Wọn ni awọn ọdọ ẹya Hausa marun un kan ni wọn wa gba lati gbe oku wọn jade lati inu kọnga naa.

Nibayii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.