US Open 2019: Bianca júwe ilé fún Serena Williams nínú ìdíje l'America

Idije to gbogo fun Bianca Andreescu naa waye ni Flushing Meadows ni New York laarin ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2019.

Bianca Andreescu jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun lati orilẹ-ede Canada lo koju agbaọjẹ Serena Williams ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ninu idije aṣekagba.

6-3; 7-5 ni wọn pada jọ gba ninu idije aṣekagba naa ni New York.

Bianca fo fun ayọ, o ni: Odun yii ni àlá mi wa sí imuṣẹ.

O ni: inu mi dun gidi, mo mọ oore nitori mo ti n tiraka tipẹ ti mo ti n woye ọjọ ti maa pade Serena Williams ninu idije.

Serena ni gbajugbaja ti gbogbo wa n wo loke ninu ere idaraya yii.

Si iyalẹnu gbogbo ero iworan to wa lori papa ni Bianca fidi Serena janle ti o si jẹ ki Serena padanu ife ẹyẹ yii lẹẹkẹrin bayii.

Serena funra rẹ gboriyin fun ọdọmọde Bianca, o ni: Inu mi dun fun Bianca, o ṣiṣẹ bi ọmọ akin nitootọ ninu idije yii.

Ta ni Binaca Andreescu?

Bianca jẹ ọmọ orilẹ-ede Canada.

Oun ni ọdọmọde ẹni akọkọ ni Canada to maa gba ami ẹyẹ idije nla bọọlu ẹlẹyin ori tabili.

Oun ni ọdọmọde ti ko tii pe ogun ọdun akọkọ to maa gba goolu Grand slam lẹyin Maria Sharapova lọdun 2006.

Oun lo tun kọkọ gba Akọkọ ṣe Slam lẹyin ọmọ Russia to gbaa lọdun 2004 ni Wimbledon

Bianca jẹ ọdọmọde to ni igbooya ati ọkan akin ninu gbogbo idawọle rẹ, eyi to han ninu idije naa.

Andreescu ni ti ẹnikẹni ba sọ fun oun pe oun a koju Serena Williams ninu idije oun maa sọ pe ẹni naa ti ya were ni.

Oun ni gbogbo aye n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara lasiko yii pe ko si ohun ti ọdọmọde ko le ṣe yanju!

Lọdun to lọ ni Bianca ja nibẹrẹ idije ti ko si si lara awọn igba akọkọ to ṣaaju ninu gbigba bọọlu ọhun.

Wo ibẹrẹ aye Bianca:

Awọn ara Romania ni obi Bianca jẹ.

Nicu ni orukó baba rẹ nigba ti iya rẹ n jẹ Maria.

Wọn lọ ṣe atipo ni orilẹ-ede Canada nibẹre ọdun 1990.

Lati kekere ni Bianca ti n gba bọọlu ẹlẹyin ori tabili ni eyi to si ti gba ami ẹyẹ bii WTA Premier ni Indian Wells ati Toronto to si gba ẹbun owo rẹpẹte si.

Bayii, Bianca n lọ ẹni karun un ni agbaye to si n lọ sile pẹlu ẹbun owo $3.85 miliọnu.

Ẹkọ nla ti Bianca fẹ ki awọn ọdọ kọ ni pe ki wọn maa di eti wọn si ariwo ọja ati pe ki wọn ma bẹru ogbontarigi ti wọn ba fẹ koju lẹnu iṣẹ wọn.

O ni oun di eti oun si ariwo ọja awọn eniyan ni bi awọn ero lori papa naa ṣe n pariwo orukọ Serena ki oun to le bori.