PDP Kogi Primaries: Tá ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yóò gbé áṣíà gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lè lọ́wọ́?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eewọ, mo kọ lati jawọ ninu idije yii - Dino

Bi awọn eniyan ṣe n foju sọna fun eto idibo lati mọ ẹni ti yoo jade dupo gomina ipinlẹ Kogi labẹ asia PDP ṣe n sunmọ ni iroyin kan jade pe Dino ti kuro ninu awọn oludije.

Dino Melaye ọkan pataki lara awọn to n dije dupo gomina naa ti ni ahesọ lasan ni pe oun ti yọwọ ninu idije naa.

Dino ti ni irọ nla ni eyi nitori pe aja kii jẹ obi, oun ko le yọ kuro bii ọmọ ọwọ̀ ninu idije naa.

Awọn wo lo n dije ninu PDP lati di gomina Kogi?

Diẹ lo ku ti idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party nipinlẹ Kogi yoo waye.

Idibo naa ni yoo ṣe atọna oludije ẹgbẹ ti yoo kopa ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2019.

Idije naa yoo pakasọ ti awọn onwoye si ti ni ko ti le si ẹnikan to le fọwọ sọya pe oun ni igba naa yoo ja mọ lọwọ.

Oludije mẹtala ni yoo kopa ninu idibo abẹle naa ti a si ri ninu wọn gomina nigba kan ri nipinlẹ Kogi, Ibrahim Wada ati gbajugbaja oloṣelu Sẹnẹtọ Dino Melaye.

Awọn oludije mọkanla miran ni wọn yoo jijọ figagbaga. Grace Adejoh nikan ni oludije obinrin to wa lara wọn.

Ipa ẹlẹyamẹya ninu idibo Kogi

Oṣelu ipinlẹ Kogi lati igba iwasẹ jẹ eleyi ti ẹya ma n ko ipa ribiribi ninu rẹ.

Bakan naa si ni ipinlẹ naa ko ti i yan obinrin sipo Gomina ri lati igba ti wọn ti ṣe idasilẹ rẹ.

Lara awọn ẹya to wa nipinlẹ naa la ti ri ẹya Igala to saaba maa n dipo gomina mu ti awọn ẹya to ku a si maa di ipo igbakeji gomina tabi omiran to ba bọ si wọn lọwọ mu.

Gomina Yahaya Bello ti ẹgbẹ APC ni gomina ẹya Ebira akọkọ ti yoo de ipo naa ti ko si jọ wi pe o fẹ fi ipo naa silẹ bayi.

Ibrahim Wada to ti jẹ Gomina tẹlẹri jẹ ẹya Igala lati Dekina ti o si fidirẹmi lọwọ Abubakar Audu ẹgbẹ PDP ninu idibo gomina to kọja.

Iku lo yọ ọwọ Audu lawo ti Yahaya Bello fi jẹ gomina gẹgẹ bi ẹni toṣe ipo keji ninu idibo abẹle ẹgbẹ.

Dino Melaye naa wa lara awọn ti o n lewaju lati ri asia ẹgbẹ PDP gba fun ipo gomina ti awọn kan si ni o ṣeeṣe ki o ri i gba.

Dino Melaye ni Sẹnẹtọ to n ṣoju Kabba/Bunu/Ijumu ni iwọ orun ipinlẹ Kogi ni ile aṣofin agba lọwọlọwọ.

BBC Yoruba yoo maa mu gbogbo nkan to n ṣẹlẹ nibẹ wa si etigbọ yin: