You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Xenophobic Attack:Àwọn ọmọ Naijiria sọ fun South Africa pé "Ó tó gẹ́"
Oriṣiriṣi iroyin lo ti gba ayelujara kan lori ikọlu to n waye lọwọ lorilẹ-ede South Africa.
Awọn ọlọpaa ilẹ South Africa ni ọwọ awọn ti tẹ eniyan mọkanlelogoji ti wọn ni i ṣe pẹlu ohun to n ṣẹlẹ yii.
Wọn ni awọn ti mu awọn eniyan wọnyii si atimọle lataari ile ati ọja awọn ajoji ti wọn n jo nina ni South Africa.
Agbegbe Jeppestown to sunmọ Johannesburg to jẹ ibudo itaja nla gan an ni iṣẹlẹ yii ti kọnilominu julọ.
Milton Nkosi to jẹ akọroyin BBC to wa ni South Africa bayii ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn eniyan lo n sa kaakiri Johannesburg.
O ni awọn oniṣẹ ibi kan n ja ṣọọbu ile itaja awọn eniyan ti wọn si n ji ọja wọn ko lọ ti wọn si n jo awọn ile itaja miran ni ina.
Milton ni eyi ti tan de awọn agbegbe miran bii Denver, Malven, Turffontein, Tembisa ati awọn adugbo miran bayii.
Awọn fọnran fidio lori ayelujara n ṣafihan bi wọn ṣe n jo ọkọ nile ita ọkọ ati awọn ile itaja miran.
Awọn agbofinro ti fọn afẹfẹ tajutaju kaakiri pẹlu ayederu ọta ibọn ki wọn le fopin si ia alo-ki-olohun-kigbe to n ṣẹlẹ lọwọ ni South Africa bayii.
Ogagun agba Elias Mawela to jẹ kọmiṣọna ọlọpaa fun ẹkun yii sọ pe awọn ti n da ohun gbogbo pada si ipo.
Titi di asiko yii ko tii si ẹni to le fidiẹ mulẹ irufẹ awọn eniyan to wa nidi iṣẹlẹ buruku yii laarin awọn olugbe South Africa.
Minista fun awọn agbofinro, Bheki Cele naa ti ṣabẹwo si awọn ibudo iṣẹlẹ ọhun.
Oun naa bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu awọn to huwa buruku yii pe o ku diẹ kaa to.