Niger Flood: Omíyalé àgbàrà ti ya ṣọ́ọ̀bù ní Niger

Bi ojo ṣe n rọ lasiko yii ni orilẹ-ede Naijiria ti ẹru omiyale n ba awọn eniyan bẹẹ naa ni ojo naa n rọ ni orilẹ-ede Niger.

Ojo arọọroda to rọ ni ọjọ kẹta, oṣu kẹsan an ọdun yii lo n jẹ ki ọkan awọn obinrin yii ma balẹ ni agbegbe Kirkissoye ni Niamey.

Orọ omiyale agbara ya ṣọọbu yii ko yọ awọn ọdọmọde silẹ ni Naimey.

Awọn naa lọ n gbọ́n iyẹpẹ fi di awọn ibi ti omu ti gba opopona to si ti n ya wọnu ile.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣe panapana ni orilẹ-ede Niger ti ko awọn eniayna kuro ni Niamey to jẹ olu ilu Niger.

won ko won lọ si ibudo ti omi ko pọ si .

Ara agbegbe Kirkissoye kan ni yi ni Niamey to n wo ile rẹ ti omi ya wọ ti ko si si nkan to le ṣe.

Akọsilẹ to peye ni wọn n ṣe fun ohun to nilo ati awọn to yẹ fun ipese fawọn to lugbadi omiyale.