Morocco Journalist: Wọ́n gbé Akọ̀ròyìn ní Morocco lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn àgbèrè àti oyún ṣíṣẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan ti dide iranlọwọ lati gbeja obinrin akọroyin yii.

Hajar Raissouni ni akọroyin Morocco ti awọn alaṣẹ ilẹ Morocco fẹsun kan pe o ṣeyun ati pe o ṣe agbere.

Orilẹ-ede Morocco jẹ orilẹ-ede ti awọn musulumi ẹlẹsin Islam pọ si pupọ.

Eṣẹ si ofin ni oyun ṣiṣẹ ni ilẹ Morocco ati iwa agbere ṣiṣẹ.

Awọn agbẹjọro ti wọn n ṣoju fun Hajara ni irọ ni wọn pa mọọ.

O ni pe Hajar lọ sile iwosan lọ ri dokita rẹ nigba ti ẹjẹ n ya lara rẹ ni ko to di pe wọn fi ọwọ ofin muu pe o ṣẹyun lai ti i ṣe igbeyawo.

Wọn tun mu afẹsọna Hajar si atimọle pẹlu awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa mẹta.

Ọpọ ọrọ ni awọn eniyan ti n sọ lori ayelujara lori ṣẹlẹ yii lai yọ awọn musulumi omiran silẹ.

Ọpọ n beere pe ṣe ẹṣe ni lati lọ ile iwosan lọ ri dokita ẹni abi kini aye n di lorukọ ẹsin to ba wu ni lati sin lọna to wu eeyan bayii?

Hajar ni akọroyin to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Akhbar Al-Yaoum.

Opọ igba ni o maa n kọ nipa ìṣe ati irinsi awọn alatako.

Ajọ Amnesty International ni mimu ti wọn muu ni ọwọ kan nipa iroyin to n kọ ninu ni eyi ti awọn agbẹjọrọ ijọba Morocco ti ni irọ ni.