Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Àkọlé fídíò, Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Ìdí ti mo ṣe kọ̀ láti lo ẹbí mi nínú àwọn fíìmù mi -Kunle Afolayan

Mo kọ̀ láti kọ́ ilé méjì láyé - Kunle Afolayan

Gbajugbaja oṣere ati oludari ere ni Kunle Afolayan to jẹ ọmọ agba ọjẹ oṣere 'Ade Love' to ti doloogbe nsiyi.

Kunle Afolayan ba BBC Yoruba sọrọ lori iriri rẹ ati igbiyanju rẹ.

O sọrọ nipa ipa ti iṣẹ obi maa n ni lori igbiyanju ọmọ wọn.

Afolayan ni oun kọ lati fi ogun silẹ de ọmọ oun nitori oun gbagbọ pe wọn maa ṣoriire ju oun lọ ti wọn fi maa ni ọ̀rọ̀ pupọ.

O yanana koko ti awọn eniyan maa n sọ lori lilo awọn aburo rẹ ninu awọn fiimu rẹ.

Kunle ni oun naa ko kuku binu pe wọn ko pe oun wa kopa ninu fiimu wọn.

O ni oun kọ lati ṣe ojuṣaju nitori ẹbi.

O ni oun ko gbagbọ ninu ẹsin igbagbọ, musulumi tabi abalaye ṣugbọn oun gba Olorun gbọ.

Ogbontarigi oṣere yii ni ayika oun ati iṣẹ ti Babab oun ṣe silẹ maa n fun oun ni iwuri lati tẹsiwaju ninu iṣẹ ti oun yan laayo.

Bakan naa lo sọ pataki gbigbe aṣa Yoruba ga to maa n hande ninu iṣẹ oun

O gba awọn eeyan niyanju pe, ti a ba bi ẹni, a maa n tun ara ẹni bi ni pẹlu apẹẹrẹ ipa ti Baba rẹ ko ninu igbesi aye rẹ.