World theatre Day: Kosoko ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọn onítíátà
Agba ọjẹ kan nidi isẹ tiata, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko laarin awọn osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ ni ẹgbẹ awọn osere ori itage lede Yoruba, taa mọ si TAMPAN, ti n se gudugudu meje, ati yaya mẹfa fun eto adojutodo fawọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho gbé ìjìjàgbara dé Osogbo, ó ṣàlàyé orísun agbára rẹ̀
- Àwọn gbajúmọ̀ faraya lórí alágbe tó kọ́ ilé mẹ̀rin, ra mọ́tò mẹ́ta
- Mímú àdínkù bá owónàá ìjọba kọ́ ni ojútùú sí ọrọ̀ ajé tó mẹ́hẹ - Tinubu
- Wo ìhùwàsí Buhari, àwọn èèkàn Nàìjíríà àti ibòmíì tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Ìgbìmọ̀ tó n gbọ́ ẹ̀sùn tako àwọn ọlọ́pàá SARS ní Eko fún opó kan àti èèyàn mẹ́ta mìí ní 16.2m Naira
- Pínpín tàbí àtúntò Nàìjíríà kọ́ ló máa mú ìgbáyé-gbádùn wá fún wa lórílẹ́èdè yìí- Amaechi
- Ohun tí Ọlọ́pàá mọ̀ nípa bóyá Agbébọn jí ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ tó ń lọ jèrè ọkàn gbé rèé!
- Ìdí tí NIN rẹ fi ṣe pàtàkì láti forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB 2021 rèé
Kosoko ni amọ irufẹ eto adojutofo yii ko ba ti waye tipẹ fawọn osere tiata Yoruba, bi kii ba se ọpọ wọn to pagi dina eto naa nigba naa, apẹyinda iwa aidaa yii si ni ọpọ wọn to n saisan n jẹ loni yii.
Jide Kosoko wa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lede Yoruba lati maa tọju ara wọn, ki wọn ma si lo gbogbo owo ti wọn n ri lati fi jẹnu tan, amọ ki wọn pọn omi silẹ de oungbẹ fun ọjọ alẹ.