Arsenal vs Valencia: Arsenal gbẹ̀san fún Liverpool, Tottenham

Arsenal ati Valencia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chelsea ni tirẹ ta ọmi pẹlu Eintranct frankfurt ni orilẹede Germany

Lẹyin idojukọ to de ba ikọ agbabọọlu Tottenham ati Liverpool ninu idije Champions league lọsẹ yii, orilẹede Gẹẹsi yi ipin rẹ pada ni idije bọọlu laaarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu ni ilẹ Yuroopu pẹlu bi ikọ agbabọọlu Arsenal ati Chelsea ṣe gbo ewuro si oju awọn iks ti wọn ba gba bọọlu ni idije UEROPA ni ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan-meji lọrọ ri fun ilẹ Gẹẹsi ninu idije bọọlu ilẹ Yuroopu. Ni ọjọ iṣẹgun ni Tottenham ti kọkọ ṣide ijiya naa nigba ti ẹgbẹ agbabọọẹu Ajax ti ilu Amsterdam lorilẹede Netherlands naa mọle pẹlu ami ayo kan.

Ni ọjọru ni Liverpool tẹwọ gba igi ijakulẹ naa nigba ti wọn fara gba goolu mẹta ni ọwọ ikọ agbabọọlu Barcelona ti orilẹede Spain.

Barcelona ati Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chelsea ni tirẹ ta ọmi pẹlu Eintranct frankfurt ni orilẹede Germany

Amọṣa, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yii ọrọ naa pada nigba ti wọn na Valencia pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan ni apapa iṣire Emirates ni ilẹ Gẹẹsi.

Goolu meji ni Lacazette gba wọle lẹyin ti agbabọọẹu Valencia, Mouctar Diakhaby ti kọkọ ṣide ajọdun goolu ni ifẹsẹwọnsẹ naa ni iṣẹju kọkanla. Aubameyang, to jẹ agbabọọlu Arsenal lo wa fi ọba lee ni aadọrun iṣẹju iufẹsẹwọnsẹ naa.

Tottehnam ati Ajax

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chelsea ni tirẹ ta ọmi pẹlu Eintranct frankfurt ni orilẹede Germany

Chelsea, ni tirẹ, ta ọmi pẹlu Eintranct frankfurt ni orilẹede Germany.

Ni ọṣẹ to n bọ lawọn ikọ orilẹede Gẹẹsi naa yoo ma mọ ohun ti ifa bọọlu fọ fun wọn. Boya yoo fọọre tabi fọbi, boya iwaju ni ọlọkọ idije Yuroopu n gbe wọn lọ tabi ẹyin.

Chelsea ati Frankfurt

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chelsea ni tirẹ ta ọmi pẹlu Eintranct frankfurt ni orilẹede Germany

Liverpool yoo koju Barcelona ni ọjọ iṣẹgun, Tottehnam yoo ba Ajax lalejo ni ọjọru ki o to kan Arsenal ati Valencia pẹlu Chelsea ati Eintranct frankfurt ni ọjọbọ ọsẹ to n bọ