Atiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà
Atiku gbà pé agbára wà lọwọ oludibo láti dibo yan oun gẹgẹ bii aarẹ Naijiria tabi ki wọn dibo yan ọ̀dọ́.
Atiku Abubakar to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ Naijiria labẹ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo n dije dupo aarẹ bayii labẹ ẹgbẹ òṣèlu People s Democratic Party.
O ṣalaye fún BBC pé oun ti n ba ọdọ ṣiṣẹ papọ tipẹ lati igba ti oun ti wa nijọba.
O ni awọn ọdọ naa lo ti di gomina kaakiri bayii.
Atiku Abubakar lasiko to n dahun ibeere lori ibi ti Naijiria ja ogun Boko Haram dé ni o ti rẹ awọn adari ologun Naijiria lasiko yii.
O ni ileeṣe ologun lapapọ ko ṣiṣẹ to mọ bi o ti yẹ.
Atiku ni kò si èrò tuntun mọ́ ninu awọn adari ologun ati pe asiko ti to ki wọn faaye gba awọn ọmọ ogun tuntun.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ PDP ninu idibo 2019 ni oun ko figba kankan dena àwọn ọdọ Naijiria lati jade dupo aarẹ to ba wu wọn.
O ni agbara wa lọwọ awọn oludibo lati yan oun tabi ki wọn dibo yan awọn ọdọ to ti jade dupo lasiko yii.