Nigeria Elections 2019: Ezekwesili ní àfojúsùn òun ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn

Àkọlé fídíò, Ezekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Obiageli Ezekwesili salaye pe, bi iṣẹ ati osi se mu awọn ọmọ orilẹede Naijiria dùndùn, se afihan pe, awọn ẹgbẹ oselu to ti tukọ orilẹede yii saaju ko lee gbe Naijiria de ebute ogo.

O ni gbogbo aye lo mọ awọn atimaasebọ oun, ti wọn ko si lee gbagbe bi oun ti se afọmọ ẹka to n gbe isẹ agbase jade, lọwọ iwa ajẹbanu lasiko ti oun wa ni Abuja.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ajafẹtọ ọmọniyan naa tun fi kun pe, ayipada nla gbọdọ ba eto ọrọ aje wa ni Naijiria, ka baa lee dagbere fun isẹ ati osi, taa si fi idagbasoke ọmọniyan rọpo iwa gbigbe ara le epo rọbi, eyi ti yoo mu ki agbega ba eto ọrọ aje wa.

Oludije fun ipo aarẹ lobinrin naa ko sai tun yan pe, aabo ẹmi ati dukia ọmọ ilẹ yii kọọkan yoo jẹ oun logun pupọ, ti oun ba wọle bii aarẹ orilẹede Naijiria, ti awujọ wa yoo si bọ lọwọ awọn iwa ọdaran loniranran, to fi mọ awọn iwa idunkooko mọni.