Europa: Arsenal, Chelsea gbáradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpele ìsọ̀rì tó kẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri ilẹ Yuroopu yoo tun kan lu papa ni ọjọbọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti o gbẹyin ninu abala isọri-isọri idije Europa ti saa ọdun 2018/2019.
Lara wọn ni awọn ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi bii Arsenal ati Chelsea.
Lootọ Arsenal ati Chelsea ti pegede fun ipele to kan, ṣugbọn awọn mejeeji ṣi n ja fun pipegede lati jawe olubori ninu isọri wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Arsenal yoo maa koju ikọ agbabọọlu FK Qarabag ni papa iṣire Emirates; nigba ti Chelsea yoo lọ ba MOL Vidi lalejo .
Olukọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Maurizio Sarri ni ifẹsẹwọnsẹ naa "le pupọ lati gbaradi fun".
Amọṣa, o ni oun yoo gbe ikọ ti ko fi bẹẹ le pupọ kalẹ fun ifẹsẹwọnsẹ naa nitori ọna ti la fun wọn pe awọn yoo bori isọri naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo le pupọ nitori pe ko si afojusun tabi ilepa to yanranti kan lori rẹ"
O fi kun un pe"Ifẹsẹwọnsẹ ti a gba ṣaaju eyi pẹlu ikọ agbabọọlu Vidi ti a bori pẹlu ami ayo kan si odo le pupọ nitori wọn di oju ile wọn daradara, o nira fun wa pupọ lati gba ayo wọ ile wọn."
Fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu naa, Unai Umery ni oun ko tii lee sọ boyaMesut Ozil yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nitori ẹyin ti o n dun un.
Amọṣa o ni Laurent Koscielny yoo kopa lẹyin ti o ti gbọn ara nu kuru ninu iṣoro iṣan ẹsẹ ti o n yọọ lẹnu.
Bakan naa lo ni Aaron Ramsey yoo kopa n inu ifẹsẹwọnsẹ naa.













