Fela Durotoye: ọmọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n tó di olóṣèlú Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @feladurotoye
Ta ni Fẹla ọmọ Durotoye?
Fun ẹni ti o ba mọ itan oṣelu orilẹ-ede Naijiria fun igba diẹ sẹyin,, orukọ Fẹla Durotoye ko lee jẹyọ gẹgẹ bii ara awọn oloṣelu atigbadegba lorilẹ-ede Naijiria.
Ọjọ kejila, oṣu karun, ọdun 1971 ni wọn bi Fẹla Durotoye gẹgẹ bii Adetokunbọ Oluwafẹọlami Durotoye.
Ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ ni baba ati iya rẹ, Layiwọla ati Adeline Durotoye ni fasiti Ibadan ki wọn to lọ si fasiti ilu Ifẹ eyi ti o ti di Obafemi Awolowo University, OAU bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ohun to yẹ ki o mọ nipa Fẹla Durotoye:
Ọrọ Fẹla Durotoye yatọ si ọpọ awọn oloṣelu nitori pupọ awọn oloṣelu lorilẹ-ede Naijiria lode oni, papa julọ awọn ti wọn n dupo aarẹ ni awọn tabi baba ati iya wọn ti wa lẹnu owo oṣelu fun ọpọlọpọ ọdun.
Ni fasiti Obafemi Awolowo yii ni Fela Durotoye ti kẹkọ gboye imọ ẹrọ Kọmputa pẹlu eto ọrọ aje ki o to tun kawe gba imọ kun imọ pẹlu ẹkọ imọ ijinlẹ keji, MBA ni fasiti OAU yii kan naa ki o to tun wa imọ lọ si gbajugbaja fasiti ni, Havard University ni orilẹ-ede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, @feladurotoye
Ogunna gbongbo onimọ nipa iṣuna ni Fẹla Durotoye.
O ti ṣiṣẹ pẹlu ọpọ ileeṣẹ ja-n-kan-ja-n-kan kaakiri agbaye bii Ventures and Trust Limited, Phillips consulting limited ki o to lọ da ileeṣẹ V.I.P Consulting limited silẹ ni ọdun 2000.

Oríṣun àwòrán, @Fela2019
Gbajugbaja onimọ ati olukọni nipa ọrọ akoso ati idari ni Fẹla Durotoye ti o si ti ṣe idanilẹkọ fun ọpọ ni ilẹ yii ati ni oke okun.
Ni bayii, Fẹla ni aarẹ ileeṣẹ GEMSTONE Nation Builders Foundation, ileeṣẹ ti ko gbara le ijọba ti ko si le ere ninu iṣẹ rẹ.
Ni oṣu kejila, ọdun 2009 ni o lewaju awọn eekan ilumọọka lagbo amuludun lorilẹ-ede Naijiria bii, Banky W, Alibaba, Kate Henshaw, Omoni Oboli, Teju Babyface, Sound Sultan, TY Bello, Dj Jimmy Jatt, Omawunmi, Denrele, Dele Momodu, Tosin Bucknor, Stella Damascus, Tee A, Segun Dangote, Ebuka Obi ati bẹẹbẹẹ lọ fun eto kan ti o pe ni "Mushin Makeover" eyi ti wọn fi tu ọpọ ile ni agbegbe Mushin nipinlẹ Eko kun fun ayika to gbayii.

Oríṣun àwòrán, @feladurotoye
Ko din ni ẹgbẹrun meji awọn eeyan ti wọn korajọ fun eto yii.
O tó bií ile mẹrindinlaadọọrun ti wọn kun. Lẹyin o rẹyin, ọgọrun un awọn ọdọ ni wọn ni ileeṣẹ apọda Berger Paints PLC kọ ni iṣẹ ile kikun lọna igbalode ti awọn pẹlu si di ẹni ti o n fi iṣẹ naa jẹun bayii.

Oríṣun àwòrán, @feladurotoye
Ni ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2018 ni Fẹla Durotoye kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lasiko idibo apapọ ọdun 2019 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Alliance for New Nigeria, ANN.
Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 2018 ni wọn yan an gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu naa.

Oríṣun àwòrán, @feladurotoye
Ṣe wọn ni eeyan bi ahun naa nii ri ahun he, gbajugbaja agbanisiṣẹ bii tirẹ, Tara Fẹla-Durotoye ni Fẹla fẹ ni iyawo.
Tara jẹ amofin ati aṣaraloge. Oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ aṣaraloge House of Tara.
Ọmọ ọkunrin mẹta ni wọn bi ti orukọ wọn a si maa jẹ Mobolurin, Demilade & Morolaoluwa.



















