Kí ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti ọ̀nà tí o leè gbà dènà rẹ̀?

Aworan bi oronro to n peelo eroja insulin ni aọ̀ ara ṣe ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aisan itọ ṣuga lee fa aisan ọkan, rọpa-rọsẹ, ifọju, idakureku kidirin tabi gige ẹsẹ

Aisan bẹmi dije to lagbara ni itọ ṣuga jẹ ti o si n gba ẹmi awọn eeyan to le ni miliọnu kan ni ọdọọdun- ko si ẹni ti ko lee ni aisan yii.

Aisan yii maa n waye nigba ti agọ ara ko ba lee ṣe atupalẹ ati amulo awọn aadun ṣuga ninu ẹjẹ; o lee fa aisan ọkan, rọpa-rọsẹ, ifọju, idakureku kidirin tabi gige ẹsẹ.

Aisan yii n fi ojojumọ gbilẹ sii ni- Nnkan bii okooleni irinwo o le meji ni awọn ọdọ to ni aisan itọ ṣuga lagbaye, gẹgẹ bi ajọ ilera lagbaye, WHO ṣe sọ ọ.

Pẹlu bi ọrọ ṣe ri yii, ilaji awọn eeyan to ni aisan yii gan ni wọn mọ wi pe awọn nii.

Kini o n fa aisan itọ ṣuga?

Eso ati awọn ounjẹ miran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aisan yii n fi ojojumọ gbilẹ sii ni

Bi a ba jẹun, agọ ara wa yoo ṣe atupalẹ rẹ si elo ṣuga fun ara. Eroja ara kan ti o n jẹ insulin eleyi ti o njade lati inu oronro ni yoo ṣeto bi agọ ara wa yoo ṣe loo fun alekun agbara.

Aworan bi arun itọ suga ṣe gbilẹ nilẹ Afirika
Àkọlé àwòrán, Aworan bi arun itọ suga ṣe gbilẹ nilẹ Afirika

Amọṣa bi eroja ara ti a n pe ni insulin yii ba kuna tabi ko ṣiṣẹ bi o ti tọ, eyi yoo maa fa akojọpọ aadun ṣuga ni inu ẹjẹ.

Irufẹ aisan itọ ṣuga wo lo wa?

  • Aisan itọ ṣuga onipile akọkọ ti a mọ si Type I: Awọn onimọ sayẹnsi ko tii le sọ ohun kan ni pato ti o n faa ti oronro ara ma fi n kuna lati ṣeto eroja insulin yii ṣugbọn wọn ni o ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn ohun ajogunba tabi kokoro agọ ara ti wọn ba ba oronro jẹ lee faa.
  • Aisan itọ ṣuga onipile keji ti a mọ si Type II: Wahala aijafafa to oronro yii a maa wọpọ laarin awọn eeyan ti wọn ti balaga tan yan-an-yan. Amọṣa awọn ewe to ba sanra asanju pẹlu tun lee ni.

Awọn obinrin miiran to loyun pẹlu a maa ni aisan yii. Itọ ṣuga alaboyun, gestational diabetes ni a n pe eyi. A maa waye nigba ti ara alaboyun ko ba lee se eroja insulin ti o to fun alaboyun ati ọmọ inu rẹ.

Awọn miiran wa ti wọn lee ni aisan ti o n tọka si itọ ṣuga. Ko tii di itọ ṣuga o, ṣugbọn o ṣi n tọka si i ni, o si lee sun kẹẹrẹ di itọ ṣuga to ba ya.

Eeeyan kan gba aya rẹ mu bi ẹni ti ọkan n dun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aisan itọ ṣuga nii ṣe pẹlu ajogunba ati awọn ohun ti o n ṣẹlẹ ni ayika ṣugbọn o lee mojuto iye aadun ṣuga ti n bẹ ninu ẹjẹ rẹ nipa ṣiṣọ jijẹ ati mimu rẹ

Kini awọn ami aisan itọ ṣuga?

Pupọ awọn ami ti o n fi aisan ṣuga han naa ni:

  • Oungbẹ omi
  • Titọ ju bi o ti yẹ lọ, paapaa julọ ni alẹ tabi oru.
  • Rirẹ ni ju bi o ti yẹ lọ
  • Ki eeyan maa ṣaa dede ru lai ni idi
  • Ki oju maa wo baibai
  • Adaajina ọgbẹ tabi egbo.

Ṣe itọ ṣuga ṣee dena?

aadun ṣun pẹ̀lu ṣibi ti o kun fun gbẹrẹfu aadun ṣuga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aadun ṣuga a maa fa alekun ṣuga ni agọ ara

Aisan itọ ṣuga nii ṣe pẹlu ajogunba ati awọn ohun ti o n ṣẹlẹ ni ayika ṣugbọn o lee mojuto iye aadun ṣuga ti n bẹ ninu ẹjẹ rẹ nipa ṣiṣọ jijẹ ati mimu rẹ pẹlu irufẹ igbe aye ti o n gbe.

Yiyẹra fun awọn ounjẹ ati ohun mimu aladun ṣuga.

Apẹẹrẹ bii iyẹfun funfun, burẹdi funfun, irẹsi funfun, ounjẹ aladun ṣuga.

Aworan to n ṣafihan bi aarun atọjẹ ṣe gbilẹ ni Afirika
Àkọlé àwòrán, Ayajọ fifi opin si arun atọgbẹ

Awọn ounjẹ bii ẹfọ, eso, ẹwa dara fun jijẹ

Ere idaraya lasiko pẹlu a maa ṣe ọpọ iṣẹ lati din iye adun ṣuga ninu ẹjẹ ku.

Bakan naa ni o dara lati yẹra fun siga mimu ati awọn ounjẹ ọlọra nitori aisan ọkan.

Kini ọwọja aisan itọ ṣuga lagbaye?

Okunrin kan n gun ara rẹ ni abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilaaji awọn eeyan to ni aisan yii gan ni wọn mọ wi pe awọn nii

Gẹgẹ bii ajọ ilera agbaye , WHO ṣe sọ, iye awọn eeyan to ni aisan itọ ṣuga ti goke lati ọgọrun miliọnu o le mẹjọ (108milion) ni ọdun 1980, iyẹn ọdun mejidinlogoji sẹyin si okooleni irinwo o le meji mílíọ̀nu ni ọdun mẹrin sẹyin, (2014)

Ni ọdun 1980, o din ni ida marun un ninu ọgọrun awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn le ni mejidinlogun ti wọn ni aisan itọ ṣuga lagbaye, eyi ti goke si ida mẹjọ abọ ninu ọgọrun (8.5%)

Aadun ṣuga a maa fa alekun ṣuga ni agọ ara
Àkọlé àwòrán, Ilaaji awọn eeyan to ni aisan yii gan ni wọn mọ wi pe awọn nii

Ajọ to mbojuto ọrọ itọ ṣuga lagbaye, The International Diabetes Federation, ni nnkan bi ida ọgọrin ninu ọgọrun, (80%) awọn ọdọ ti o ni aisan yii ni wọn jẹ ọdọ langba ti wọn si wa lati awọn orilẹede ti ko ri ọwọ họ ori lagbaye nibi ti atijẹ ati mu ko tii dan mọran to.