Awọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Anambra ti ń jànfàni #5000

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Láìpẹ́ yìí ní ìjọba àpapọ̀ kéde láti máà san ẹgbẹ̀rún márùn-ún gba fún àwọn tálaákà lórìlẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Owó yìí ni yóò jẹ́ atọ́nà sáájú pínpín owó Abacha ti wọ́n rí gbà fún àwọn ènìyàn.

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti wa dí òòtọ́ọ́ báyìí bí ètò náà ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹwu, àwọn ènìyàn kan ní abúlé Ifitedunu, ni ìjọba ìbílẹ̀ Dunukofia nípinlẹ̀ Anambra ló jẹ́ri si ọ̀rọ̀ yìí nígbà ti wọn ń bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìjọba Nàìjíríà ń san ẹgbẹ̀rún márùn-ún márùn-ún fún awọn ènìyàn to tálákà jùlọ ní orílẹ̀-èdè yìí.

Àjọ̀ tó ń rí sí pínpín owó nílè ìjọba àpapọ ló ń ri kí ìlú náà, wọn ni àwọn ṣe ìforúkọ sílẹ̀ nítorí pé ìpele àkọ́kọ́ kò kan àwọn míràn.

Awọn to gba owó náà sàlàyé fún BBC Pidgin pé àwọn ti gba owó náà bí ẹ̀mẹ́fà báyìí àti pé oṣooṣù ni wọn máà ń fun àwọn ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá.

Wọn ni ẹgbẹ́run márùn ọ̀hún kò tó ǹkankan sùgbọ́n ogún ẹgbẹrun náírà yóò wúlò fun gbogbo ǹkan ti àwọn bá fẹ́ fi ṣe.

Bó tilè jẹ́ pe àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò PDP ti sọ pé àrékereke òṣèlú lásán ni ọ̀rọ̀ owó náà.

Kìí ṣe gbogbo ìpínlẹ ni owó náà ti de báyìí sùgbọn àwọn àjọ to ń ri sí àmúludùn àti ààbo àrá-ìlú (NASSCO) ti ń lọ káàkiri láti gba orúkọ sílẹ̀ nígbà ti àjọ tó ń ri sí pínpín owó náà yóò máa san owó.

Èto ọ̀hún jẹ́ ti Banki àgbáyé láti ran àwọn orilẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí ìpín àwọn aláìní ènìyàn baà lè dínkù, sùgbọn wọn ni àwọn ń fi ojú sí owó náà láti rii dájú pé magòmágó ò wáyé.

Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọdún 20 tí Abacha kú

Ogun ọdun ti kọja lẹyin ti Ọgagun Sani Abacha to jẹ adari orilẹ-ede Naijiria lọdun 1993 si 1998 ku iku ojiji.

Sani Abacha to jẹ ọmọ bibi ilu Kanuri lati ipinlẹ Borno. O lọ si ile iwe ọlogun ti Kaduna ko to gba oye ọgagun lọdun 1963.

Titi di oni to jẹ ayajọ ọjọ ti oloogbe naa papoda, ọ̀pọ̀ awọn ọmọ Naijiria ko sọ nkan rere nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara

Awọn miran sọ pe ọwọ lile ni Abacha fi se ijọba nigba aye rẹ, ti ọpọlọpọ ajafẹtọ ọmọ eniyan sọ pe o ru ofin to de ihuwa si ara ilu.

Awọn miran fẹsun kan an pe, o lu ọpọlọpọ owo ilu ni ponpo nigba aye rẹ, ati pe awọn eniyan gbagbọ pe obinrin lo se iku pa a.

Amọ, Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ati awọn ọmọ Naijiria miran gbagbọ pe asiko rẹ tu eniyan lara nitori ipese ohun amayedẹrun bii ina ijọba, ọna to gbooro, ẹkọ ọfẹ ati eto ilera fun awọn eniyan.