EKITI 2018: APC, PDP ń gbéná wojú ara wọn lórí ìpolongo ìbò

Ẹgbẹ oṣelu APC ti kọminu lori bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe n ṣe ipolongo ibo rẹ lawọn ile ẹkọ ijọba nipinlẹ Ekiti.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti, Taiwo Ọlatunbọsun ṣalaye ninu atẹjade kan nilu Ado Ekiti pe bi ikọ ipolongo idibo PDP ṣe n lọ kaakiri awọn ile ẹkọ lasiko to yẹ ki awọn akẹkọọ maa kọ ẹkọ lati polongo ibo ko buyi fun eto oṣelu ijọba awarawa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

APC ni bi PDP ṣe n lọ kaakiri awọn ile iwe naa fihan pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo n lo awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko tii tọjọ ati dibo nipinlẹ Ekiti.

"O ṣeni laanu pe awọn akẹkọọ to yẹ ki wọn maa gbaradi fun idanwo aṣekagba wọn ni awọn eeyan wọnyii n lo lati fi ṣe òwò aitọ wọn fun eto idibo."

Bakan naa ni APC l'Ekiti tun fẹsun kan PDP ati gomina Ayọdele Fayọṣe pe wọn bẹ awọn olukọ kan lọwẹ lati maa lọ kaakiri lati dunkooko mọ awọn olukọ miran lati gba kaadi idibo wọn.

Amọṣa, Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, ti sọ pe 'aisan ibẹru ijakulẹ idibo' lo n da ẹgbẹ oṣelu APC laamu.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ekiti, Lere Ọlayinka, ninu atẹjade kan iha ti Ọmọwe Kayọde Fayẹmi kọ sawọn oṣiṣẹ nigba to kọkọ jẹ gomina lo n baa lẹru.

O ni igbakeji gomina, Ọjọgbọn Kọlapọ OIuṣọla, to je kọmiṣọna fun eto ẹkọ nipinlẹ naa laṣẹ gẹgẹ bii ipò rẹ lati lọ ṣabẹwo si awọn ile iwe.