Ìsekúpani darandaran; ọlọ́pàá mẹ́rin forí káásà ní Benue

Fulani darandaran kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iroyin sọ pe awakọ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn k'agbako nipinlẹ Ondo

Ọlọọpa mẹrin ti papoda lẹyin ikọlu awọn agbebọn si ibudo awọn ọlọọpa ni ipinlẹ Benue, ti eniyan mọkanla si ti di awati.

Isẹlẹ naa waye nigba ti awọn ọlọọpa n wa ọkọ kaakiri ni agbeegbe Anyibe titi to fi de ijọba ibilẹ Ayilamọ ni ipinlẹ Benue.

Ile isẹ ọlọọpa ipinlẹ naa gba ẹnu agbẹnusọ wọn, ASP Moses Yamu sọwipe lati ibẹrẹ ọdun yii ni ikọlu awọn Fulani darandaran ti n waye lagbeegbe naa, ti ọpọlọpọ ẹmi si ti ba isẹlẹ naa lọ.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Arakunrin yamu sọwipe adari ajọ ọlọọpa, Ibrahim Idris ti ran awọn ikọ ọlọọpa to n wa ọkọ ofurufu si agbeegbe naa lati se iwadi ofintoto nipa isẹlẹ naa

Agbẹnusọ ile isẹ ipinlẹ Benue naa wa fikun wipe ajọ ọlọọpa yoo sa ipa wọn lati ri wipe ọwọ tẹ awọn asekupani naa, ti wọn yoo si foju wina ijọba.